Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 15:1-5

Orin atunilára ti Dáfídì. 15  Jèhófà, ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ?+ Ta ni yóò máa gbé ní òkè ńlá mímọ́ rẹ?+   Ẹni tí ń rìn láìlálèébù,+ tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù+ Tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+   Kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́,+ Kò ṣe ohun búburú kankan sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀,+ Kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ojúlùmọ̀ rẹ̀ tímọ́tímọ́.+   Ní ojú rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí kò ní láárí jẹ́ ẹni tí a kọ̀,+ Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ó ń bọlá fún.+ Ó ti búra sí ohun tí ó burú fún ara rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kò yí padà.+   Kò fi owó rẹ̀ fúnni ní èlé,+ Kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.+ Ẹni tí ó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, a kì yóò mú un ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé