Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 149:1-9

149  Ẹ yin Jáà!+Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+Àti ìyìn rẹ̀ nínú ìjọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin.+   Kí Ísírẹ́lì máa yọ̀ nínú Olùṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá,+Àwọn ọmọ Síónì—kí wọ́n kún fún ìdùnnú nínú Ọba wọn.+   Kí wọ́n máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀.+Kí wọ́n máa fi ìlù tanboríìnì àti háàpù kọ orin atunilára sí i.+   Nítorí tí Jèhófà ní ìdùnnú sí àwọn ènìyàn rẹ̀.+Ó ń fi ìgbàlà ṣe àwọn ọlọ́kàn tútù lẹ́wà.+   Kí àwọn adúróṣinṣin máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú ògo;Kí wọ́n máa fi ìdùnnú ké jáde lórí ibùsùn wọn.+   Kí àwọn orin tí ń kókìkí Ọlọ́run wà ní ọ̀fun wọn,+Kí idà olójú méjì sì wà ní ọwọ́ wọn,+   Láti gbẹ̀san ní kíkún lára àwọn orílẹ̀-èdè,+Àwọn ìbáwí mímúná lára àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè,+   Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn+Àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ irin de àwọn ẹni àyìnlógo wọn,   Láti mú àwọn ìpinnu ìdájọ́ tí a kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ ní kíkún sí wọn lára.+Irú ọlá ńlá bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti gbogbo àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.+Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé