Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 148:1-14

148  Ẹ yin Jáà!+Ẹ yin Jèhófà láti ọ̀run,+Ẹ yìn ín ní àwọn ibi gíga.+   Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀.+Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.+   Ẹ yìn ín, oòrùn àti òṣùpá.+Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.+   Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọ̀run àwọn ọ̀run,+Àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ lókè ọ̀run.+   Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà;+Nítorí pé òun fúnra rẹ̀ ni ó pàṣẹ, a sì dá wọn.+   Ó sì mú kí wọ́n dúró títí láé, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+Ó ti fún wọn ní ìlànà, èyí tí kì yóò sì ré kọjá.+   Ẹ yin Jèhófà láti ilẹ̀ ayé,+Ẹ̀yin ẹran ńlá abàmì inú òkun àti gbogbo ẹ̀yin ibú omi,+   Ẹ̀yin iná àti yìnyín, ìrì dídì àti èéfín nínípọn,+Ìwọ ẹ̀fúùfù oníjì líle, tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,+   Ẹ̀yin òkè ńláńlá àti gbogbo ẹ̀yin òkè kéékèèké,+Ẹ̀yin igi eléso àti gbogbo ẹ̀yin kédárì,+ 10  Ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ àti gbogbo ẹ̀yin ẹran agbéléjẹ̀,+Ẹ̀yin ohun tí ń rákò àti ẹ̀yin ẹyẹ abìyẹ́lápá,+ 11  Ẹ̀yin ọba ilẹ̀ ayé+ àti gbogbo ẹ̀yin àwùjọ orílẹ̀-èdè,Ẹ̀yin ọmọ aládé+ àti gbogbo ẹ̀yin onídàájọ́ ilẹ̀ ayé,+ 12  Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin+ àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú,+Ẹ̀yin arúgbó+ pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọdékùnrin.+ 13  Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà,+Nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ó ga ré kọjá ibi tí ó ṣeé dé.+Iyì rẹ̀ ń bẹ lókè ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.+ 14  Òun yóò sì gbé ìwo àwọn ènìyàn rẹ̀ ga,+Ìyìn gbogbo àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,+Ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn tí ó sún mọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.+Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé