Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 147:1-20

147  Ẹ yin Jáà,+ Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run wa;+ Nítorí tí ó dùn mọ́ni—ìyìn yẹ ẹ́.+   Jèhófà ń kọ́ Jerúsálẹ́mù;+ Àwọn tí a fọ́n ká lára Ísírẹ́lì ni ó ń kó jọpọ̀.+   Ó ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn+ lára dá,+ Ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.+   Ó ka iye àwọn ìràwọ̀;+ Gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ wọn pè.+   Olúwa wa tóbi, ó sì pọ̀ yanturu ní agbára;+ Òye rẹ̀ ré kọjá ríròyìn lẹ́sẹẹsẹ.+   Jèhófà ń mú ìtura bá àwọn ọlọ́kàn tútù;+ Ó ń rẹ àwọn ẹni burúkú wá sí ilẹ̀.+   Ẹ fi ìdúpẹ́ dá Jèhófà lóhùn;+ Ẹ fi háàpù kọ orin atunilára sí Ọlọ́run wa,+   Ẹni tí ń fi àwọsánmà bo ojú ọ̀run,+ Ẹni tí ń pèsè òjò fún ilẹ̀ ayé,+ Ẹni tí ń mú kí àwọn òkè ńláńlá rú koríko tútù jáde.+   Ó ń fi oúnjẹ àwọn ẹranko fún wọn,+ Fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò tí ń ké.+ 10  Òun kò ní inú dídùn sí agbára ńlá tí ẹṣin ní,+ Bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìdùnnú sí ẹsẹ̀ ènìyàn.+ 11  Jèhófà ní ìdùnnú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,+ Sí àwọn tí ń dúró de inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.+ 12  Gbóríyìn fún Jèhófà,+ ìwọ Jerúsálẹ́mù. Máa yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Síónì.+ 13  Nítorí pé ó ti sọ ọ̀pá ìdábùú àwọn ẹnubodè rẹ di alágbára; Ó ti bù kún àwọn ọmọ rẹ ní àárín rẹ.+ 14  Ó fi àlàáfíà sí ìpínlẹ̀ rẹ;+ Ó ń fi ọ̀rá àlìkámà tẹ́ ọ lọ́rùn.+ 15  Ó ń fi àsọjáde rẹ̀ ránṣẹ́ sí ilẹ̀ ayé;+ Ìyára kánkán ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń sáré. 16  Ó ń fúnni ní ìrì dídì bí irun àgùntàn;+ Ìrì dídì wínníwínní ni ó ń tú ká bí eérú.+ 17  Ó ń ju omi dídì rẹ̀ bí òkèlè.+ Ta ní lè dúró níwájú òtútù rẹ̀?+ 18  Ó ń rán ọ̀rọ̀+ rẹ̀ jáde, ó sì ń yọ́ wọn. Ó ń mú kí ẹ̀fúùfù rẹ̀ fẹ́;+ Omi ń sẹ̀. 19  Ó ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Jékọ́bù,+ Ó ń sọ àwọn ìlànà+ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì.+ 20  Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn;+ Àti ní ti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀, wọn kò mọ̀ wọ́n.+ Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé