Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 145:1-21

Ìyìn, ti Dáfídì. א [Áléfì] 145  Ṣe ni èmi yóò gbé ọ ga, ìwọ Ọlọ́run mi Ọba,+ Ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún orúkọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+ ב [Bétì]   Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún ọ,+ Ṣe ni èmi yóò máa yin orúkọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+ ג [Gímélì]   Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi,+ Àwámáridìí sì ni títóbi rẹ̀.+ ד [Dálétì]   Ìran dé ìran yóò máa gbóríyìn fún àwọn iṣẹ́ rẹ,+ Àwọn ìṣe agbára ńlá rẹ ni wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+ ה [Híì]   Ọlá ńlá ológo ti iyì rẹ+ Àti ọ̀ràn nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ ni èmi yóò fi ṣe ìdàníyàn mi.+ ו [Wọ́ọ̀]   Wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa okun àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù rẹ;+ Àti ní ti títóbi rẹ, ṣe ni èmi yóò máa polongo rẹ̀.+ ז [Sáyínì]   Wọn yóò máa fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ yanturu oore rẹ,+ Wọn yóò sì fi ìdùnnú ké jáde nítorí òdodo rẹ.+ ח [Kétì]   Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú,+ Ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.+ ט [Tétì]   Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò,+ Àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.+ י [Yódì] 10  Gbogbo iṣẹ́ rẹ ni yóò máa gbé ọ lárugẹ, Jèhófà,+ Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò sì máa fi ìbùkún fún ọ.+ כ [Káfì] 11  Wọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa ògo ipò ọba rẹ,+ Wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára ńlá rẹ,+ ל [Lámédì] 12  Láti sọ àwọn ìṣe agbára ńlá rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn+ Àti ògo ọlá ńlá ipò ọba rẹ̀.+ מ [Mémì] 13  Ipò ọba rẹ jẹ́ ipò ọba tí ó wà fún gbogbo àkókò tí ó lọ kánrin,+ Àgbègbè ìṣàkóso rẹ sì jẹ́ jálẹ̀ gbogbo ìran-ìran tí ń dìde ní ṣísẹ̀-ń-tẹ̀lé.+ ס [Sámékì] 14  Jèhófà ń fún gbogbo àwọn tí ó ṣubú ní ìtìlẹyìn,+ Ó sì ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde.+ ע [Áyínì] 15  Ìwọ ni ojú gbogbo gbòò ń wò tìrètí-tìrètí,+ Ìwọ sì ń fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò rẹ̀.+ פ [Péè] 16  Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ,+ Ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.+ צ [Sádì] 17  Olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ Ó sì jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.+ ק [Kófì] 18  Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,+ Nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́.+ ר [Réṣì] 19  Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ,+ Igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.+ ש [Ṣínì] 20  Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ Ṣùgbọ́n gbogbo ẹni burúkú ni òun yóò pa rẹ́ ráúráú.+ ת [Tọ́ọ̀] 21  Ẹnu mi yóò máa sọ̀rọ̀ ìyìn Jèhófà;+ Kí gbogbo ẹran ara sì máa fi ìbùkún fún orúkọ mímọ́ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé