Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 144:1-15

Ti Dáfídì. 144  Ìbùkún ni fún Jèhófà Àpáta mi,+ Ẹni tí ń kọ́ ọwọ́ mi fún ìjà,+ Àti ìka mi fún ogun;   Inú rere mi onífẹ̀ẹ́ àti ibi odi agbára mi,+ Ibi gíga ààbò mi àti Olùpèsè àsálà fún mi,+ Apata+ mi àti Ẹni tí mo sá di,+ Ẹni tí ń tẹ àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.+   Jèhófà, kí ni ènìyàn jẹ́, tí ìwọ fi ń kíyè sí i,+ Àní ọmọ ẹni kíkú,+ tí ìwọ fi ń gba tirẹ̀ rò?   Ènìyàn tìkára rẹ̀ jọ èémí àmíjáde lásán-làsàn;+ Àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bí òjìji tí ń kọjá lọ.+   Jèhófà, tẹ ọ̀run rẹ wálẹ̀ kí o lè sọ̀ kalẹ̀;+ Fọwọ́ kan àwọn òkè ńláńlá kí wọ́n lè rú èéfín.+   Mú kí mànàmáná kọ, kí o lè tú wọn ká;+ Rán àwọn ọfà rẹ jáde, kí o lè kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+   Na ọwọ́ rẹ jáde láti ibi gíga;+ Dá mi sílẹ̀ lómìnira, kí o sì dá mi nídè lọ́wọ́ omi púpọ̀,+ Kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,+   Àwọn tí ẹnu wọn ń sọ ohun àìjóòótọ́,+ Àwọn tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.+   Ọlọ́run, orin tuntun ni èmi yóò máa kọ sí ọ.+ Ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá ni èmi yóò máa fi kọ orin atunilára sí ọ,+ 10  Ẹni tí ń fún àwọn ọba ní ìgbàlà,+ Ẹni tí ń dá Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ idà tí ń ṣeni léṣe.+ 11  Dá mi sílẹ̀ lómìnira, kí o sì dá mi nídè ní ọwọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,+ Àwọn tí ẹnu wọn ti sọ ohun àìjóòótọ́,+ Àwọn tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké,+ 12  Àwọn tí ó wí pé: “Àwọn ọmọkùnrin wa dà bí àwọn ọ̀gbìn kéékèèké tí ó dàgbà ní ìgbà èwe wọn,+ Àwọn ọmọbìnrin wa dà bí àwọn igun-igun tí a gbẹ́ bí ọnà ààfin, 13  Àwọn àró wa kún, wọ́n ń mú ọ̀kan-kò-jọ̀kan èso jáde,+ Àwọn agbo ẹran wa ń pọ̀ sí i ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ọ̀kan ń di ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá, ní àwọn ojú pópó wa, 14  Ẹrù ń wọ àwọn ẹran ọ̀sìn wa lọ́rùn, láìsí yíya èyíkéyìí, oyún kò sì ṣẹ́ lára wọn,+ Kò sì sí igbe ẹkún rárá ní àwọn ojúde ìlú wa.+ 15  Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ fún!” Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé