Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 143:1-12

Orin atunilára ti Dáfídì. 143  Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;+ Fi etí sí àrọwà mi.+ Nínú ìṣòtítọ́ rẹ, dá mi lóhùn nínú òdodo rẹ.+   Má sì wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ;+ Nítorí tí kò sí alààyè kankan tí ó lè jẹ́ olódodo níwájú rẹ.+   Nítorí pé ọ̀tá ti lépa ọkàn mi;+ Ó ti tẹ ẹ̀mí mi mọ́ ilẹ̀yílẹ̀.+ Ó ti mú kí n máa gbé ní àwọn ibi tí ó ṣókùnkùn bí àwọn tí ó ti kú fún àkókò tí ó lọ kánrin.+   Àárẹ̀ sì mú ẹ̀mí+ mi nínú mi; Ọkàn-àyà mi ti kú tipiri nínú mi.+   Mo ti rántí àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn;+ Mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ;+ Tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.+   Mo ti tẹ́ ọwọ́ mi sí ọ;+ Ọkàn mi dà bí ilẹ̀ gbígbẹ táútáú sí ọ.+ Sélà.   Ṣe wéré, dá mi lóhùn, Jèhófà.+ Ẹ̀mí mi ti wá sí òpin.+ Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi,+ Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe ni èmi yóò dà bí àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.+   Mú kí n gbọ́ inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ní òwúrọ̀,+ Nítorí tí èmi gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+ Mú mi mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí n máa rìn,+ Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.+   Dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Jèhófà.+ Ọ̀dọ̀ rẹ ni mo fara pa mọ́ sí.+ 10  Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,+ Nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi.+ Ẹ̀mí rẹ dára;+ Kí ó máa ṣamọ̀nà mi ní ilẹ̀ ìdúróṣánṣán.+ 11  Nítorí orúkọ rẹ,+ Jèhófà, kí o pa mí mọ́ láàyè.+ Nínú òdodo rẹ,+ kí o mú ọkàn mi jáde kúrò nínú wàhálà.+ 12  Àti nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, kí o pa àwọn ọ̀tá mi lẹ́nu mọ́;+ Kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí ọkàn mi run,+ Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ ni mí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé