Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 142:1-7

Másíkílì. Ti Dáfídì, nígbà tí ó wà nínú hòrò.+ Àdúrà. 142  Jèhófà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí fi ohùn mi ké pè fún ìrànlọ́wọ́;+Jèhófà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí fi ohùn mi ké bá fún ojú rere.+   Mo ń bá a nìṣó ní títú ìdàníyàn mi jáde níwájú rẹ̀;+Mo ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ nípa wàhálà mi níwájú rẹ̀.+   Nígbà tí àárẹ̀ mú ẹ̀mí+ mi nínú mi.Nígbà náà, ìwọ alára mọ òpópónà mi.+Ipa ọ̀nà tí mo ń rìn+Ni wọ́n fi pańpẹ́ pa mọ́ sí dè mí.+   Wo ọwọ́ ọ̀tún, kí o sì rí iPé kò sí ẹnì kankan tí ó mọyì mi rárá.+Ibi ìsásí mi ti ṣègbé kúrò lọ́dọ̀ mi;+Kò sí ẹnì kankan tí ń wádìí nípa ọkàn mi.+   Jèhófà, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.+Mo wí pé: “Ìwọ ni ibi ìsádi mi,+Ìpín+ mi ní ilẹ̀ àwọn alààyè.”+   Fetí sí igbe ìpàrọwà mi,+Nítorí tí mo ti di òtòṣì gidigidi.+Dá mi nídè lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi,+Nítorí pé wọ́n lágbára jù mí.+   Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú àjà ilẹ̀+Láti gbé orúkọ rẹ lárugẹ.+Kí àwọn olódodo kóra jọ yí mi ká,+Nítorí pé ìwọ bá mi lò lọ́nà tí ó bá a mu.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé