Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 141:1-10

Orin atunilára ti Dáfídì. 141  Jèhófà, mo ti ké pè ọ́.+Ṣe kánkán wá sọ́dọ̀ mi.+Fi etí sí ohùn mi nígbà tí mo bá pè ọ́.+   Kí a pèsè àdúrà mi sílẹ̀ bí tùràrí+ níwájú rẹ,+Àti gbígbé tí mo gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè bí ọrẹ ẹbọ ọkà ìrọ̀lẹ́.+   Jèhófà, yan ẹ̀ṣọ́ fún ẹnu mi;+Yan ìṣọ́ síbi ilẹ̀kùn ètè mi.+   Má tẹ ọkàn-àyà mi síhà ohunkóhun tí ó burú,+Láti máa bá a lọ nínú fífi ìwà burúkú ṣe àwọn ìṣe olókìkí burúkú+Pẹ̀lú àwọn aṣenilọ́ṣẹ́,+Kí n má bàa fi àwọn àdídùn wọn bọ́ ara mi.+   Bí olódodo bá gbá mi, yóò jẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́;+Bí ó bá sì fi ìbáwí tọ́ mi sọ́nà, yóò jẹ́ òróró ní orí,+Èyí tí orí mi kì yóò fẹ́ láti kọ̀.+Nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, àdúrà mi pàápàá yóò wà nígbà àwọn ìyọnu àjálù wọn.+   Àwọn onídàájọ́ wọn ni a ti bì ṣubú lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpáta gàǹgà,+Ṣùgbọ́n wọ́n ti gbọ́ àwọn àsọjáde mi, pé wọ́n dùn mọ́ni.+   Bí ìgbà tí ènìyàn bá ń la nǹkan sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí ó sì ń la nǹkan sí wẹ́wẹ́ lórí ilẹ̀ ayé,Egungun wa ni a ti tú ká ní ẹnu Ṣìọ́ọ̀lù.+   Bí ó ti wù kí ó rí, ojú mi ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+Ìwọ ni mo sá di.+Má ṣe tú ọkàn mi jáde.+   Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mú pańpẹ́ tí wọ́n ti dẹ dè mí,+Àti kúrò lọ́wọ́ ìdẹkùn àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.+ 10  Àwọn ẹni burúkú yóò já sínú àwọ̀n ara wọn lápapọ̀,+Nígbà tí èmi, ní tèmi, yóò kọjá lọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé