Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 140:1-13

Fún olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 140  Gbà mí sílẹ̀, Jèhófà, lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;+Kí o fi ìṣọ́ ṣọ́ mi àní lọ́wọ́ oníwà ipá,+   Àwọn tí ó ti pète-pèrò àwọn ohun búburú nínú ọkàn-àyà wọn,+Àwọn tí ń gbéjà kò mí láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ bí ẹni pé nínú àwọn ogun.+   Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ti ejò;+Oró paramọ́lẹ̀ abìwo wà lábẹ́ ètè wọn.+ Sélà.   Pa mí mọ́, Jèhófà, lọ́wọ́ ẹni burúkú;+Kí o fi ìṣọ́ ṣọ́ mi àní lọ́wọ́ oníwà ipá,+Àwọn tí ó ti pète-pèrò láti taari àwọn ìṣísẹ̀ mi.+   Àwọn tí ó gbé ara wọn ga ti fi pańpẹ́ pa mọ́ dè mí;+Àwọn ìjàrá sì ni wọ́n ti nà jáde gẹ́gẹ́ bí àwọ̀n lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ọ̀nà.+Àwọn ìdẹkùn ni wọ́n ti dẹ dè mí.+ Sélà.   Mo wí fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.+Jèhófà, fi etí sí ohùn ìpàrọwà mi.”+   Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ okun ìgbàlà mi,+Ìwọ ti dáàbò bo orí mi ní ọjọ́ agbo ọmọ ogun adìhámọ́ra.+   Jèhófà, má yọ̀ǹda àwọn ìfàsí-ọkàn ẹni burúkú fún un.+Má ṣagbátẹrù ìdìmọ̀lù rẹ̀, kí a má bàa gbé wọn ga.+ Sélà.   Ní ti orí àwọn tí ó yí mi ká,+Kí ìjàngbọ̀n ètè wọn bò wọ́n.+ 10  Kí a da ẹyín iná sí wọn lórí.+Jẹ́ kí a mú kí wọ́n ṣubú sínú iná,+ sínú àwọn kòtò olómi, kí wọ́n má bàa dìde.+ 11  Ẹlẹ́nu-ún-gbọ̀rọ̀—má ṣe jẹ́ kí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ilẹ̀ ayé.+Oníwà ipá—jẹ́ kí ibi pàápàá máa fi ìsọ́gọ léraléra ṣọdẹ rẹ̀.+ 12  Èmi mọ̀ dunjú pé Jèhófà yóò ṣe+Ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, èyíinì ni ìdájọ́ àwọn òtòṣì.+ 13  Dájúdájú, àwọn olódodo pàápàá yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;+Àwọn adúróṣánṣán yóò máa gbé níwájú rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé