Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 14:1-7

Sí olùdarí. Ti Dáfídì. 14  Òpònú sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “Jèhófà kò sí.”+ Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun,+ wọ́n ti hùwà lọ́nà ìṣe-họ́ọ̀-sí nínú ìbálò wọn. Kò sí ẹni tí ń ṣe rere.+   Ní ti Jèhófà, ó bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wo àwọn ọmọ ènìyàn,+ Láti rí bóyá ẹnikẹ́ni wà tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye, ẹnikẹ́ni tí ń wá Jèhófà.+   Gbogbo wọn ti yapa,+ gbogbo wọn pátá jẹ́ ẹni ìbàjẹ́;+ Kò sí ẹni tí ń ṣe rere,+ Kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan.+   Kò ha sí ìkankan lára àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ tí ó ní ìmọ̀ ni,+ Tí wọ́n ń jẹ àwọn ènìyàn mi bí ẹní ń jẹ oúnjẹ?+ Wọn kò tilẹ̀ ké pe Jèhófà.+   Ibẹ̀ ni wọ́n ti kún fún ìbẹ̀rùbojo ńláǹlà,+ Nítorí pé Jèhófà ń bẹ láàárín ìran olódodo.+   Ète ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ni ẹ ń kó ìtìjú bá, Nítorí pé Jèhófà ni ibi ìsádi rẹ̀.+   Ìgbàlà Ísírẹ́lì ì bá jẹ́ jáde wá láti Síónì!+ Nígbà tí Jèhófà bá kó àwọn òǹdè lára àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ padà,+ Kí Jékọ́bù kún fún ìdùnnú, kí Ísírẹ́lì yọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé