Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 139:1-24

Fún olùdarí. Ti Dáfídì. Orin atunilára. 139  Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí.+   Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi.+Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré.+   Ìrìn àjò mi àti ìnàtàntàn mi lórí ìdùbúlẹ̀ ni ìwọ ti díwọ̀n,+Ìwọ sì ti wá mọ gbogbo ọ̀nà mi dunjú.+   Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,+Ṣùgbọ́n, wò ó! Jèhófà, ìwọ ti mọ gbogbo rẹ̀ tẹ́lẹ̀.+   Lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ ti sàga tì mí;Ìwọ sì gbé ọwọ́ rẹ lé mi.   Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àgbàyanu gidigidi fún mi.+Ó ga sókè tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ọwọ́ mi kò fi lè tẹ̀ ẹ́.+   Ibo ni mo lè lọ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ,+Ibo sì ni mo lè fẹsẹ̀ fẹ lọ kúrò ní ojú rẹ?+   Bí mo bá gòkè re ọ̀run, ibẹ̀ ni ìwọ yóò wà;+Bí mo bá sì ga àga ìrọ̀gbọ̀kú mi ní Ṣìọ́ọ̀lù, wò ó! ìwọ yóò wà níbẹ̀.+   Bí mo bá mú ìyẹ́ apá+ tí ó jẹ́ ti ọ̀yẹ̀,Kí n lè máa gbé nínú òkun jíjìnnàréré jù lọ,+ 10  Ibẹ̀, pẹ̀lú, ni ọwọ́ rẹ yóò ti ṣamọ̀nà mi,+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbá mi mú.+ 11  Bí mo bá sì wí pé: “Dájúdájú, òkùnkùn pàápàá yóò sáré gbá mi mú!”+Nígbà náà, òru yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ yí mi ká.+ 12  Àní òkùnkùn pàápàá kì yóò ṣú jù fún ọ,+Ṣùgbọ́n òru pàápàá yóò tàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀sán ti ń tàn;+Òkùnkùn náà tilẹ̀ lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀.+ 13  Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ ni ó ṣe àwọn kíndìnrín mi;+Ìwọ ni ó yà mí sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá mi.+ 14  Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.+Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,+Bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.+ 15  Àwọn egungun mi kò pa mọ́ fún ọ+Nígbà tí a ṣẹ̀dá mi ní ìkọ̀kọ̀,+Nígbà tí a hun mí ní àwọn apá ìsàlẹ̀ jù lọ+ ní ilẹ̀ ayé. 16  Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi,+Inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀,Ní ti àwọn ọjọ́ tí a ṣẹ̀dá wọn,+Tí ìkankan lára wọn kò sì tíì sí. 17  Nítorí náà, lójú mi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣe iyebíye o!+Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn pátápátá mà pọ̀ o!+ 18  Ká ní mo fẹ́ gbìyànjú láti kà wọ́n ni, wọ́n pọ̀ ju àwọn egunrín iyanrìn pàápàá.+Mo jí, síbẹ̀síbẹ̀ mo ṣì wà pẹ̀lú rẹ.+ 19  Ọlọ́run, ì bá ṣe pé ìwọ yóò pa ẹni burúkú!+Nígbà náà, àwọn ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀+ pàápàá yóò lọ kúrò lọ́dọ̀ mi dájúdájú, 20  Àwọn tí ń sọ àwọn nǹkan nípa rẹ ní ìbámu pẹ̀lú èrò-ọkàn wọn;+Wọ́n ti lo orúkọ rẹ lọ́nà tí kò ní láárí+—àwọn elénìní rẹ.+ 21  Èmi kò ha kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ lọ́nà gbígbóná janjan, Jèhófà,+Èmi kò ha sì ní ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ?+ 22  Ìkórìíra pátápátá ni mo fi kórìíra wọn.+Wọ́n ti di ọ̀tá gidi sí mi.+ 23  Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi.+Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè,+ 24  Kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi,+Kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà+ àkókò tí ó lọ kánrin.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé