Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 138:1-8

Ti Dáfídì. 138  Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ.+ Iwájú àwọn ọlọ́run mìíràn ni èmi yóò ti máa kọ orin atunilára sí ọ.+   Èmi yóò tẹrí ba síhà tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ,+ Èmi yóò sì gbé orúkọ rẹ lárugẹ,+ Nítorí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́+ àti nítorí òótọ́ rẹ.+ Nítorí pé ìwọ ti gbé àsọjáde+ rẹ ga lọ́lá àní lékè gbogbo orúkọ rẹ.+   Ní ọjọ́ tí mo pè, ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn;+ Ìwọ bẹ̀rẹ̀ sí fi okun sọ mí di aláìṣojo nínú ọkàn mi.+   Gbogbo ọba ilẹ̀ ayé yóò gbé ọ lárugẹ, Jèhófà,+ Nítorí tí wọn yóò ti gbọ́ àwọn àsọjáde ẹnu rẹ.   Wọn yóò sì máa kọrin nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà,+ Nítorí pé ògo Jèhófà pọ̀.+   Nítorí pé Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀;+ Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.+   Bí mo bá rìn nínú wàhálà, ìwọ yóò pa mí mọ́ láàyè.+ Ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ nítorí ìbínú àwọn ọ̀tá mi,+ Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí là.+   Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò ṣe àṣepé ohun tí ó ṣàǹfààní fún mi.+ Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Má ṣe kọ àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé