Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 137:1-9

137  Lẹ́bàá àwọn odò Bábílónì+—ibẹ̀ ni a jókòó.+ Àwa sì sunkún nígbà tí a rántí Síónì.+   Orí àwọn igi pọ́pílà+ tí ń bẹ ní àárín rẹ̀ Ni a gbé àwọn háàpù+ wa kọ́.   Nítorí pé níbẹ̀, àwọn tí ó mú wa ní òǹdè béèrè àwọn ọ̀rọ̀ orin+ lọ́wọ́ wa, Àti àwọn tí ń fi wá ṣe ẹlẹ́yà—wọ́n béèrè fún ayọ̀ yíyọ̀+ pé: “Ẹ kọ ọ̀kan lára àwọn orin Síónì fún wa.”+   Báwo ni àwa ṣe lè kọ orin Jèhófà+ Ní ilẹ̀ òkèèrè?+   Bí èmi bá gbàgbé rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù,+ Kí ọwọ́ ọ̀tún mi gbàgbé.   Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu mi,+ Bí èmi kì yóò bá rántí rẹ,+ Bí èmi kì yóò bá mú kí Jerúsálẹ́mù gòkè Ré kọjá olórí ìdí tí mo ní fún ayọ̀ yíyọ̀.+   Jèhófà, rántí+ ọjọ́ Jerúsálẹ́mù+ ní ti àwọn ọmọ Édómù,+ Àwọn tí ó wí pé: “Tú u sí borokoto! Tú u sí borokoto dé ìpìlẹ̀ àárín rẹ̀!”+   Ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì, tí a ó fi ṣe ìjẹ,+ Aláyọ̀ ni ẹni náà yóò jẹ́, tí yóò san án fún ọ+ Pẹ̀lú irú ìlòsíni tìrẹ tí o fi bá wa lò.+   Aláyọ̀ ni ẹni náà yóò jẹ́, tí yóò gbá ọ mú, tí yóò sì fọ́+ Àwọn ọmọ rẹ túútúú mọ́ àpáta gàǹgà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé