Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 136:1-26

136  Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+   Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+   Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+   Fún Ẹni tí ń dá ṣe àwọn ohun ńlá, tí ó jẹ́ àgbàyanu:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+   Fún Ẹni tí ó fi òye ṣẹ̀dá ọ̀run:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+   Fún Ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé sórí omi:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+   Fún Ẹni tí ó ṣẹ̀dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+   Àní oòrùn láti máa jọba lé ọ̀sán:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+   Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ láti máa jùmọ̀ jọba lé òru:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 10  Fún Ẹni tí ó ṣá Íjíbítì balẹ̀ nínú àwọn àkọ́bí wọn:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 11  Àti Ẹni tí ó mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàárín wọn:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 12  Nípa ọwọ́ líle àti nípa apá nínà jáde:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin; 13  Fún Ẹni tí ó ya Òkun Pupa sí apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 14  Tí ó sì mú kí Ísírẹ́lì gba àárín rẹ̀ kọjá:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 15  Tí ó sì gbọn Fáráò àti ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ dànù sínú Òkun Pupa:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 16  Fún Ẹni tí ó mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ rin aginjù kọjá:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 17  Fún Ẹni tí ó ṣá àwọn ọba ńlá balẹ̀:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 18  Tí ó sì tẹ̀ síwájú láti pa àwọn ọba ọlọ́lá ńlá:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 19  Àní Síhónì ọba àwọn Ámórì pàápàá:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 20  Àti Ógù ọba Báṣánì:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 21  Tí ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni gẹ́gẹ́ bí ogún:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 22  Bí ogún fún Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 23  Ẹni tí ó rántí wa nínú ipò rírẹlẹ̀ wa:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 24  Tí ó sì já wa gbà léraléra kúrò lọ́wọ́ àwọn elénìní wa:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 25  Ẹni tí ń fi oúnjẹ fún gbogbo ẹlẹ́ran ara:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 26  Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run:+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé