Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 135:1-21

135  Ẹ yin Jáà!+ Ẹ yin orúkọ Jèhófà,+ Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,+   Ẹ̀yin tí ń dúró nínú ilé Jèhófà,+ Nínú àwọn àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.+    Ẹ yin Jáà, nítorí tí Jèhófà jẹ́ ẹni rere.+ Ẹ kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ̀, nítorí tí ó dùn mọ́ni.+   Nítorí pé Jáà ti yan Jékọ́bù fún ara rẹ̀,+ Ó ti yan Ísírẹ́lì fún àkànṣe dúkìá rẹ̀.+   Nítorí tí èmi alára mọ̀ dáadáa pé Jèhófà tóbi,+ Olúwa wa sì ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.+   Ohun gbogbo tí Jèhófà ní inú dídùn sí láti ṣe ni ó ti ṣe+ Ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé, ní òkun àti gbogbo ibú omi.+   Ó ń mú kí oruku lọ sókè láti ìkángun ilẹ̀ ayé;+ Àní ó ti ṣe àwọn ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ fún òjò;+ Ó ń mú ẹ̀fúùfù jáde wá láti inú àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ̀,+   Ẹni tí ó ṣá àwọn àkọ́bí Íjíbítì balẹ̀,+ Àti ènìyàn àti ẹranko.+   Ó rán àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sáàárín rẹ, ìwọ Íjíbítì,+ Sára Fáráò àti sára gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀;+ 10  Ẹni tí ó ṣá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè balẹ̀,+ Tí ó sì pa àwọn ọba tí ó jẹ́ alágbára gíga,+ 11  Àní Síhónì ọba àwọn Ámórì+ Àti Ógù ọba Báṣánì+ Àti gbogbo àwọn ìjọba Kénáánì,+ 12  Ẹni tí ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni gẹ́gẹ́ bí ogún,+ Bí ogún fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 13  Jèhófà, orúkọ rẹ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Jèhófà, ìrántí rẹ jẹ́ láti ìran dé ìran.+ 14  Nítorí tí Jèhófà yóò gba ẹjọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ rò,+ Yóò sì kẹ́dùn àní nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 15  Fàdákà àti wúrà ni òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè,+ Iṣẹ́ ọwọ́ ará ayé.+ 16  Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ nǹkan kan;+ Wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè rí nǹkan kan;+ 17  Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè fi etí sí nǹkan kan.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò sí ẹ̀mí kankan ní ẹnu wọn.+ 18  Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóò dà bí àwọn gan-an,+ Gbogbo ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+ 19  Ilé Ísírẹ́lì, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+ Ilé Áárónì, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+ 20  Ilé Léfì, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+ Ẹ̀yin olùbẹ̀rù Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+ 21  Ìbùkún ni fún Jèhófà láti Síónì wá,+ Ẹni tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù.+ Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé