Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 132:1-18

Orin Ìgòkè. 132  Jèhófà, rántí nípa Dáfídì+Gbogbo títẹ́ tí a tẹ́ ẹ lógo;+   Bí ó ti búra fún Jèhófà,+Bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ẹni Alágbára+ Jékọ́bù+ pé:   “Dájúdájú, èmi kì yóò lọ sínú àgọ́ ilé mi.+Èmi kì yóò gorí àga ìnàyìn tí ń bẹ nínú yàrá ìrọ̀gbọ̀kú mi títóbi lọ́lá,+   Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,+Tàbí ìtòògbé fún ojú mi títàn yanran,+   Títí èmi yóò fi rí ibì kan fún Jèhófà,+Àgọ́ ìjọsìn títóbi lọ́lá fún Ẹni Alágbára Jékọ́bù.”+   Wò ó! Àwa ti gbọ́ nípa rẹ̀ ní Éfúrátà,+Àwa ti rí i ní àwọn pápá inú igbó.+   Ẹ jẹ́ kí a wá sínú àgọ́ ìjọsìn rẹ̀ títóbi lọ́lá;+Ẹ jẹ́ kí a tẹrí ba níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.+   Dìde, Jèhófà, sí ibi ìsinmi rẹ,+Ìwọ àti àpótí+ okun rẹ.+   Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ alára,+Kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sì máa fi ìdùnnú ké jáde.+ 10  Ní tìtorí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ,+Má ṣe yí ojú ẹni àmì òróró rẹ padà.+ 11  Jèhófà ti búra fún Dáfídì,+Lóòótọ́, kì yóò fà sẹ́yìn kúrò nínú rẹ̀+ pé:“Lára èso ikùn rẹ+Ni èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ.+ 12  Bí àwọn ọmọ rẹ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́+Àti àwọn ìránnilétí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,+Títí láé ni àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú+Yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ rẹ.”+ 13  Nítorí pé Jèhófà ti yan Síónì;+Ó ti yánhànhàn fún un gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún ara rẹ̀+ pé: 14  “Èyí ni ibi ìsinmi mi títí láé;+Ìhín ni èmi yóò máa gbé, nítorí pé mo ti yánhànhàn fún un.+ 15  Àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ ni èmi yóò bù kún láìkùnà.+Àwọn òtòṣì rẹ̀ ni èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ lọ́rùn.+ 16  Àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ni èmi yóò fi ìgbàlà wọ̀;+Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ yóò sì fi ìdùnnú ké jáde láìkùnà. 17  Ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú kí ìwo Dáfídì yọ.+Mo ti ṣètò fìtílà fún ẹni àmì òróró mi.+ 18  Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀;+Ṣùgbọ́n adé dáyádémà+ rẹ̀ yóò gbilẹ̀ lórí rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé