Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 130:1-8

Orin Ìgòkè. 130  Láti inú ibú ni mo ti ké pè ọ́, Jèhófà.+   Jèhófà, gbọ́ ohùn mi.+ Kí etí rẹ sì ṣí sí ohùn ìpàrọwà mi.+   Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́,+ Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?+   Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ,+ Kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.+   Mo ti ṣèrètí, Jèhófà, ọkàn mi ti ṣèrètí,+ Mo sì ti dúró de ọ̀rọ̀ rẹ̀.+   Ọkàn mi ti dúró de Jèhófà+ Ju bí àwọn olùṣọ́ ti ń dúró de òwúrọ̀,+ Tí wọ́n ń wọ̀nà fún òwúrọ̀.+   Kí Ísírẹ́lì máa bá a nìṣó ní dídúró de Jèhófà.+ Nítorí pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bẹ lọ́dọ̀ Jèhófà,+ Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ yanturu ìtúnràpadà sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.+   Òun tìkára rẹ̀ yóò sì tún Ísírẹ́lì rà padà kúrò nínú gbogbo ìṣìnà rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé