Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 13:1-6

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 13  Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí ìwọ yóò fi gbàgbé mi?+ Ṣé títí láé ni?+Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi ojú rẹ pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi?+   Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò ṣe ìdènà nínú ọkàn mi,Ẹ̀dùn-ọkàn nínú ọkàn-àyà mi ní ọ̀sán?Yóò ti pẹ́ tó tí a óò gbé ọ̀tá mi ga lé mi lórí?+   Wò mí; dá mi lóhùn, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi.Mú kí ojú mi tàn,+ kí n má bàa sùn lọ nínú ikú,+   Kí ọ̀tá mi má bàa sọ pé: “Mo ti borí rẹ̀!”Kí àwọn elénìní mi má bàa kún fún ìdùnnú nítorí pé a mú kí n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.+   Ní tèmi, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé;+Jẹ́ kí ọkàn-àyà mi kún fún ìdùnnú nínú ìgbàlà rẹ.+   Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti bá mi lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé