Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 129:1-8

Orin Ìgòkè. 129  “Ó ti pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n ti ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi láti ìgbà èwe mi wá,”+ Ni kí Ísírẹ́lì máa wí nísinsìnyí,+   “Ó ti pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n ti ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi láti ìgbà èwe mi wá;+ Síbẹ̀, wọn kò tíì borí mi.+   Àwọn atúlẹ̀ ti túlẹ̀ lórí ẹ̀yìn mi pàápàá;+ Wọ́n ti mú àwọn aporo wọn gùn.”   Olódodo ni Jèhófà.+ Ó ti ké ìjàrá àwọn ẹni burúkú sí wẹ́wẹ́.+   Ojú yóò tì wọ́n, wọn yóò sì yí padà,+ Gbogbo àwọn tí ó kórìíra Síónì.+   Wọn yóò dà bí koríko tútù ti orí òrùlé,+ Èyí tí ó jẹ́ pé, kí a tó tu ú kúrò, ó ti gbẹ dànù,+   Èyí tí akárúgbìn kò fi kún ọwọ́ rẹ̀,+ Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń kó ìtí jọ kò fi kún oókan àyà rẹ̀.   Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé: “Kí ìbùkún Jèhófà wà lórí yín.+ Àwa ti bù kún yín ní orúkọ Jèhófà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé