Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 127:1-5

Orin Ìgòkè. Ti Sólómọ́nì. 127  Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà,+Lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.+Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá ṣọ́ ìlú ńlá náà,+Lásán ni ẹ̀ṣọ́ wà lójúfò.+   Lásán ni ẹ ń dìde ní kùtùkùtù,+Tí ẹ ń pẹ́ kí ẹ tó jókòó,+Tí ẹ ń fi ìrora jẹ oúnjẹ.+Bẹ́ẹ̀ gan-an ni òun ń fi oorun fún olùfẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n.+   Wò ó! Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà;+Èso ikùn jẹ́ èrè.+   Bí àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá,+Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà èwe rí.+   Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó fi wọ́n kún+ apó rẹ̀.Ojú kì yóò tì wọ́n,+Nítorí tí wọn yóò bá àwọn ọ̀tá sọ̀rọ̀ ní ẹnubodè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé