Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 126:1-6

Orin Ìgòkè. 126  Nígbà tí Jèhófà kó àwọn òǹdè Síónì jọ padà,+Àwa dà bí àwọn tí ń lá àlá.+   Ní àkókò yẹn, ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,+Ahọ́n wa sì kún fún igbe ìdùnnú.+Ní àkókò yẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè+ pé:“Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wọn.”+   Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wa.+Àwa ti kún fún ìdùnnú.+   Jèhófà, kó ẹgbẹ́ àwọn òǹdè wa jọ padà,+Bí ojú ìṣàn omi ní Négébù.+   Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn+Yóò fi igbe ìdùnnú ká a.+   Láìkùnà, ẹni tí ń jáde lọ, àní tí ó ń sunkún,+Bí ó ti gbé irúgbìn ẹ̀kún àpò dání,+Láìkùnà, yóò fi igbe ìdùnnú wọlé wá,+Bí ó ti gbé àwọn ìtí rẹ̀ dání.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé