Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 125:1-5

Orin Ìgòkè. 125  Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+ Dà bí Òkè Ńlá Síónì,+ tí a kò lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ṣùgbọ́n tí ó ń bẹ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+   Jerúsálẹ́mù—bí àwọn òkè ńlá ti yí i ká,+ Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yí àwọn ènìyàn rẹ̀ ká+ Láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.+   Nítorí pé ọ̀pá aládé ti ìwà burúkú kì yóò máa bá a nìṣó ní wíwà+ lórí ìpín àwọn olódodo, Kí àwọn olódodo má bàa na ọwọ́ wọn lé ìwà àìtọ́ kankan.+   Jèhófà, ṣe rere sí àwọn ẹni rere,+ Àní sí àwọn tí ó jẹ́ adúróṣánṣán nínú ọkàn-àyà wọn.+   Ní ti àwọn tí ń yà sí àwọn ọ̀nà wíwọ́ ti ara wọn,+ Jèhófà yóò mú kí wọ́n lọ pẹ̀lú àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.+ Àlàáfíà yóò wà lórí Ísírẹ́lì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé