Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 124:1-8

Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì. 124  “Ọpẹ́lọpẹ́ pé Jèhófà wà fún wa,”+Ni kí Ísírẹ́lì máa wí nísinsìnyí,+   “Ọpẹ́lọpẹ́ pé Jèhófà wà fún wa+Nígbà tí àwọn ènìyàn dìde sí wa,+   Nígbà náà, wọn ì bá ti gbé wa mì àní láàyè,+Nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa.+   Nígbà náà, omi pàápàá ì bá ti gbé wa lọ,+Àní ọ̀gbàrá ì bá ti kọjá lórí ọkàn wa.+   Nígbà náà, omi ìkùgbù+Ì bá ti kọjá lórí ọkàn wa.   Ìbùkún ni fún Jèhófà, tí kò fi wá fún wọn+Gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ fún eyín wọn.+   Ọkàn wa dà bí ẹyẹ tí ó ti yè bọ́+Lọ́wọ́ pańpẹ́ àwọn tí ń dẹ ìjẹ̀.+Pańpẹ́ ti ṣẹ́,+Àwa alára sì ti yè bọ́.+   Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ nínú orúkọ Jèhófà,+Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé