Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 123:1-4

Orin Ìgòkè. 123  Ìwọ ni mo gbé ojú mi sókè sí,+Ìwọ tí ń gbé ní ọ̀run.+   Wò ó! Bí ojú àwọn ìránṣẹ́ ti ń wo ọwọ́ ọ̀gá wọn,+Bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti ń wo ọwọ́ olúwa rẹ̀ obìnrin,+Bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Jèhófà Ọlọ́run wa,+Títí yóò fi fi ojú rere hàn sí wa.+   Fi ojú rere hàn sí wa, Jèhófà, fi ojú rere hàn sí wa;+Nítorí pé a ti fi ìfojú-tín-ín-rín rọ wá yó dẹ́múdẹ́mú.+   A ti fi ìfiniṣẹ̀sín àwọn tí ó wà ní ìdẹ̀rùn rọ ọkàn wa yó dẹ́múdẹ́mú,+Àní ìfojú-tín-ín-rín níhà ọ̀dọ̀ àwọn olùṣe fọ́ńté.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé