Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 122:1-9

Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì. 122  Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé:+ “Jẹ́ kí a lọ+ sí ilé Jèhófà.”+   Ẹsẹ̀ wa dúró+ Nínú àwọn ẹnubodè rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.+   Jerúsálẹ́mù jẹ́ èyí tí a kọ́ bí ìlú ńlá+ Tí a ti so pọ̀ nínú ìṣọ̀kanṣoṣo,+   Ibi tí àwọn ẹ̀yà gòkè lọ,+ Àwọn ẹ̀yà Jáà,+ Gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí fún Ísírẹ́lì+ Láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ Jèhófà.+   Nítorí pé ibẹ̀ ni a gbé àwọn ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀ sí,+ Àwọn ìtẹ́ fún ilé Dáfídì.+   Ẹ béèrè fún àlàáfíà Jerúsálẹ́mù.+ Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ ìlú ńlá, yóò bọ́ lọ́wọ́ àníyàn.+   Kí àlàáfíà máa bá a lọ nínú ohun àfiṣe-odi rẹ,+ Àti òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn nínú àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ.+   Nítorí àwọn arákùnrin mi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi ni èmi yóò ṣe sọ̀rọ̀ wàyí pé:+ “Kí àlàáfíà wà nínú rẹ.”+   Nítorí ilé Jèhófà Ọlọ́run wa,+ Ṣe ni èmi yóò máa wá ire fún ọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé