Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 121:1-8

Orin Ìgòkè. 121  Èmi yóò gbé ojú mi sókè sí àwọn òkè ńlá.+ Ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?+   Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá,+ Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.+   Kò ṣeé ṣe kí òun jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+ Kò ṣeé ṣe kí Ẹni tí ń ṣọ́ ọ tòògbé.+   Wò ó! Kì yóò tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sùn,+ Ẹni tí ń ṣọ́ Ísírẹ́lì.+   Jèhófà ń ṣọ́ ọ.+ Jèhófà ni ibòji+ rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+   Àní oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ọ̀sán,+ Tàbí òṣùpá ní òru.+   Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ gbogbo ìyọnu àjálù.+ Òun yóò máa ṣọ́ ọkàn rẹ.+   Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ìjáde rẹ àti ìwọlé rẹ+ Láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé