Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 120:1-7

Orin Ìgòkè. 120  Jèhófà ni mo ké pè nínú wàhálà mi,+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn.+   Jèhófà, dá ọkàn mi nídè lọ́wọ́ ètè èké,+ Lọ́wọ́ ahọ́n àgálámàṣà.+   Kí ni ènìyàn yóò fi fún ọ, kí sì ni ènìyàn yóò fi kún un fún ọ, Ìwọ ahọ́n àgálámàṣà?+   Àwọn ọfà mímú ti alágbára ńlá,+ Pa pọ̀ pẹ̀lú ẹyín iná àwọn igi wíwẹ́.+   Mo gbé, nítorí pé mo ti ṣe àtìpó ní Méṣékì!+ Mo ti pàgọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgọ́ Kídárì.+   Fún àkókò pípẹ́ gan-an ni ọkàn mi ti fi pàgọ́+ Pẹ̀lú àwọn olùkórìíra àlàáfíà.+   Èmi dúró fún àlàáfíà;+ ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀,+ Wọ́n wà fún ogun.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé