Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 12:1-8

Sí olùdarí lórí ọ́kítéfì ìsàlẹ̀.+ Orin atunilára ti Dáfídì. 12  Gbà mí là,+ Jèhófà, nítorí pé ẹni ìdúróṣinṣin ti wá sí òpin;+Nítorí pé àwọn olùṣòtítọ́ ti pòórá kúrò nínú àwọn ọmọ ènìyàn.   Àìṣòótọ́ ni olúkúlùkù wọ́n ń bá ara wọn sọ;+Ètè dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in+ ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀, àní pẹ̀lú ọkàn-àyà méjì.+   Jèhófà yóò ké gbogbo ètè dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in kúrò,Ahọ́n tí ń sọ àwọn ohun ńláńlá,+   Àwọn tí ó ti wí pé: “Ahọ́n wa ni àwa yóò fi borí.+Ètè wa ń bẹ pẹ̀lú wa. Ta ni yóò jẹ́ ọ̀gá fún wa?”   “Nítorí fífi àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ṣe ìjẹ, nítorí ìmí ẹ̀dùn àwọn òtòṣì,+Èmi yóò dìde lọ́tẹ̀ yìí,” ni Jèhófà wí.+“Èmi yóò fi í sínú ipò àìséwu kúrò lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá wú fùkẹ̀ sí i.”+   Àwọn àsọjáde Jèhófà jẹ́ àsọjáde mímọ́ gaara,+Bí fàdákà tí a yọ́ mọ́ nínú ìléru ìyọ́rin ti ilẹ̀, tí a mú mọ́ kedere ní ìgbà méje.   Ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà, yóò máa ṣọ́ wọn;+Ìwọ yóò pa olúkúlùkù mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìran yìí fún àkókò tí ó lọ kánrin.   Àwọn ẹni burúkú ń rìn yí ká ibi gbogbo,Nítorí pé a gbé ìwà búburú jáì ga láàárín àwọn ọmọ ènìyàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé