Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 119:1-176

א [Áléfì] 119  Aláyọ̀ ni àwọn aláìní-àléébù ní ọ̀nà wọn,+ Àwọn tí ń rìn nínú òfin Jèhófà.+   Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ mọ́;+ Wọ́n ń fi gbogbo ọkàn-àyà wá a.+   Ní ti tòótọ́, wọn kò fi àìṣòdodo kankan ṣe ìwà hù.+ Àwọn ọ̀nà rẹ̀ ni wọ́n ń rìn.+   Ìwọ tìkára rẹ ti fi àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ fúnni lọ́nà àṣẹ,+ Láti máa fi tọkàntara pa á mọ́.+   Ì bá ṣe pé àwọn ọ̀nà mi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in+ Láti máa pa àwọn ìlànà rẹ mọ́!+   Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ojú kì yóò tì mí,+ Nígbà tí mo bá gbára lé gbogbo àṣẹ rẹ.+   Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ nínú ìdúróṣánṣán ọkàn-àyà,+ Nígbà tí mo bá kọ́ àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo.+   Àwọn ìlànà rẹ ni mo ń pa mọ́.+ Má fi mí sílẹ̀ pátápátá.+ ב [Bétì]   Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin+ ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.+  10  Gbogbo ọkàn-àyà mi ni mo ti fi wá ọ.+ Má ṣe mú kí n ṣáko lọ kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+  11  Inú ọkàn-àyà mi ni mo fi àsọjáde rẹ ṣúra sí,+ Kí n má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.+  12  Ìbùkún ni fún ọ, Jèhófà. Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+  13  Mo ti fi ètè mi polongo+ Gbogbo ìpinnu ìdájọ́ ẹnu rẹ.+  14  Èmi ti yọ ayọ̀ ńláǹlà ní ọ̀nà àwọn ìránnilétí rẹ,+ Gan-an gẹ́gẹ́ bí lórí gbogbo àwọn ohun oníyelórí yòókù.+  15  Ṣe ni èmi yóò máa fi àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ ṣe ìdàníyàn mi,+ Èmi yóò sì máa gbára lé àwọn ipa ọ̀nà rẹ.+  16  Nítorí pé èmi yóò fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ.+ Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.+ ג [Gímélì]  17  Gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó bá a mu sí ìránṣẹ́ rẹ, kí n lè wà láàyè,+ Kí n sì lè máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+  18  La ojú mi, kí n lè máa wo+ Àwọn ohun àgbàyanu láti inú òfin rẹ.+  19  Àtìpó lásán ni mí lórí ilẹ̀.+ Má fi àwọn àṣẹ rẹ pa mọ́ fún mi.+  20  Ọkàn mi ni a ti bò mọ́lẹ̀ nítorí yíyánhànhàn+ Fún àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ ní gbogbo ìgbà.+  21  Ìwọ ti bá àwọn oníkùgbù tí a gégùn-ún fún wí lọ́nà mímúná,+ Àwọn tí ń ṣáko lọ kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+  22  Yí ẹ̀gàn àti ìfojú-tín-ín-rín kúrò lára mi,+ Nítorí pé mo ti pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́.+  23  Àní àwọn ọmọ aládé jókòó; wọ́n bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì lòdì sí mi.+ Ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ìlànà rẹ ni ìdàníyàn rẹ̀.+  24  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ìránnilétí rẹ ni mo ní ìfẹ́ni fún,+ Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ràn mi.+ ד [Dálétì]  25  Ọkàn mi ti ń lẹ̀ mọ́ ekuru.+ Pa mí mọ́ láàyè ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.+  26  Mo ti polongo àwọn ọ̀nà mi, kí o lè dá mi lóhùn.+ Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+  27  Mú mi lóye ọ̀nà àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ,+ Kí n lè máa fi àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ ṣe ìdàníyàn mi.+  28  Ọkàn mi kò lè sùn nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.+ Gbé mi dìde ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.+  29  Mú ọ̀nà èké pàápàá kúrò lọ́dọ̀ mi,+ Kí o sì fi òfin rẹ ṣe ojú rere sí mi.+  30  Ọ̀nà ìṣòtítọ́ ni mo ti yàn.+ Àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ ni mo kà sí ohun yíyẹ.+  31  Mo ti rọ̀ mọ́ àwọn ìránnilétí rẹ.+ Jèhófà, má ṣe kó ìtìjú bá mi.+  32  Èmi yóò sáré àní ní ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ,+ Nítorí tí ìwọ mú kí ọkàn-àyà mi ní àyè.+ ה [Híì]  33  Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni ní ọ̀nà àwọn ìlànà rẹ,+ Kí n lè máa pa á mọ́ títí dé orí èyí tí ó kẹ́yìn.+  34  Mú mi lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,+ Kí n sì lè máa fi gbogbo ọkàn-àyà pa á mọ́.+  35  Mú kí n máa rìn ní ipa ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ,+ Nítorí tí mo ní inú dídùn sí i.+  36  Tẹ ọkàn-àyà mi síhà àwọn ìránnilétí rẹ,+ Kí ó má sì jẹ́ sí èrè.+  37  Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí;+ Pa mí mọ́ láàyè ní ọ̀nà tìrẹ.+  38  Mú àsọjáde rẹ ṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ,+ Tí ó tẹ̀ sí bíbẹ̀rù rẹ.+  39  Mú kí ẹ̀gàn mi kọjá lọ, èyí tí mo fòyà,+ Nítorí pé àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ dára.+  40  Wò ó! Mo ń yánhànhàn fún àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ.+ Nínú òdodo rẹ, pa mí mọ́ láàyè.+ ו [Wọ́ọ̀]  41  Kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ tọ̀ mí wá, Jèhófà,+ Ìgbàlà rẹ ní ìbámu pẹ̀lú àsọjáde rẹ,+  42  Kí n lè fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ń gàn mí lóhùn,+ Nítorí tí mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ.+  43  Má sì mú ọ̀rọ̀ òtítọ́ kúrò ní ẹnu mi pátápátá,+ Nítorí pé mo ti dúró de ìpinnu ìdájọ́ tìrẹ.+  44  Ṣe ni èmi yóò máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo,+ Fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+  45  Ṣe ni èmi yóò máa rìn káàkiri ní ibi tí ó ní àyè gbígbòòrò,+ Nítorí pé mo ti wá àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ pàápàá.+  46  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ṣe ni èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí rẹ ní iwájú àwọn ọba,+ Ojú kì yóò sì tì mí.+  47  Èmi yóò sì fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn àṣẹ rẹ,+ Tí mo ti nífẹ̀ẹ́.+  48  Èmi yóò sì gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè sí àwọn àṣẹ rẹ, tí mo ti nífẹ̀ẹ́,+ Ṣe ni èmi yóò máa fi àwọn ìlànà rẹ ṣe ìdàníyàn mi.+ ז [Sáyínì]  49  Rántí ọ̀rọ̀ tí a sọ fún ìránṣẹ́ rẹ,+ Èyí tí ìwọ mú mi dúró dè.+  50  Èyí ni ìtùnú mi nínú ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́,+ Nítorí pé àsọjáde tìrẹ ti pa mí mọ́ láàyè.+  51  Àwọn oníkùgbù pàápàá ti fi mí ṣẹ̀sín dé góńgó.+ Èmi kò yapa kúrò nínú òfin rẹ.+  52  Jèhófà, mo rántí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ láti àkókò tí ó lọ kánrin,+ Mo sì rí ìtùnú fún ara mi.+  53  Àní ìgbónára tí ó kún fún ìhónú ti gbá mi mú nítorí àwọn ẹni burúkú,+ Tí ń fi òfin rẹ sílẹ̀.+  54  Orin atunilára ni àwọn ìlànà rẹ jẹ́ fún mi+ Ní ilé tí mo ti ń ṣe àtìpó.+  55  Ní òru, mo rántí orúkọ rẹ, Jèhófà,+ Kí n lè pa òfin rẹ mọ́.+  56  Àní èyí ti di tèmi, Nítorí pé àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ ni mo ti pa mọ́.+ ח [Kétì]  57  Jèhófà ni ìpín mi;+ Mo ti ṣèlérí láti máa pa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+  58  Mo ti fi gbogbo ọkàn-àyà mi tù ọ́ lójú.+ Fi ojú rere hàn sí mi ní ìbámu pẹ̀lú àsọjáde rẹ.+  59  Mo ti gbé àwọn ọ̀nà mi yẹ̀ wò,+ Kí n lè yí ẹsẹ̀ mi padà sí àwọn ìránnilétí rẹ.+  60  Mo ṣe wéré, n kò sì jáfara+ Láti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+  61  Àní ìjàrá àwọn ẹni burúkú yí mi ká.+ Òfin rẹ ni èmi kò gbàgbé.+  62  Ní ọ̀gànjọ́ òru, mo dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ+ Nítorí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo.+  63  Alájọṣe ni mo jẹ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,+ Àti pẹ̀lú àwọn tí ń pa àṣẹ ìtọ́ni rẹ mọ́.+  64  Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ti kún ilẹ̀ ayé.+ Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+ ט [Tétì]  65  Ní tòótọ́, ìwọ ti bá ìránṣẹ́ rẹ lò dáadáa,+ Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.+  66  Kọ́ mi ní ìwà rere,+ ìlóyenínú+ àti ìmọ̀ pàápàá,+ Nítorí pé mo ti lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn àṣẹ rẹ.+  67  Kí n tó bọ́ sábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́, mo ń ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀,+ Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo ti pa àsọjáde rẹ gan-an mọ́.+  68  Ẹni rere ni ọ́, o sì ń ṣe rere.+ Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+  69  Àwọn oníkùgbù ti fi èké rẹ́ mi lára.+ Ní tèmi, gbogbo ọkàn-àyà mi ni èmi yóò máa fi pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ mọ́.+  70  Ọkàn-àyà wọn ti di aláìnímọ̀lára gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá.+ Èmi, ní tèmi, ti ní ìfẹ́ni fún òfin rẹ.+  71  Ó dára fún mi pé a ti ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́,+ Kí n lè kọ́ àwọn ìlànà rẹ.+  72  Òfin+ ẹnu rẹ dára fún mi,+ Pàápàá ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà àti fàdákà lọ.+ י [Yódì]  73  Ọwọ́ ìwọ fúnra rẹ ni ó ṣẹ̀dá mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ Mú mi lóye, kí n lè kọ́ àwọn àṣẹ rẹ.+  74  Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni àwọn tí ó rí mi tí wọ́n sì ń yọ̀,+ Nítorí pé mo ti dúró de ọ̀rọ̀ rẹ.+  75  Èmi mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé òdodo ni àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ+ Àti pé nínú ìṣòtítọ́ ni o ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́.+  76  Jọ̀wọ́, kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ kí ó tù mí nínú,+ Ní ìbámu pẹ̀lú àsọjáde rẹ fún ìránṣẹ́ rẹ.+  77  Kí àánú rẹ tọ̀ mí wá, kí n lè máa wà láàyè nìṣó;+ Nítorí pé òfin rẹ ni ohun tí mo ní ìfẹ́ni fún.+  78  Kí ojú ti àwọn oníkùgbù, nítorí pé wọ́n ṣì mí lọ́nà láìnídìí.+ Ní tèmi, àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ ni mo fi ṣe ìdàníyàn mi.+  79  Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sọ́dọ̀ mi,+ Àti àwọn tí ó mọ àwọn ìránnilétí rẹ pẹ̀lú.+  80  Kí ọkàn-àyà mi jẹ́ aláìní-àléébù nínú àwọn ìlànà rẹ,+ Kí ojú má bàa tì mí.+ כ [Káfì]  81  Ọkàn mi ti joro lẹ́nu wíwọ̀nà fún ìgbàlà rẹ;+ Nítorí pé mo ti dúró de ọ̀rọ̀ rẹ.+  82  Ojú mi ti joro lẹ́nu wíwọ̀nà fún àsọjáde rẹ,+ Bí mo ti ń wí pé: “Ìgbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”+  83  Nítorí pé mo dà bí ìgò awọ+ nínú èéfín. Àwọn ìlànà rẹ ni èmi kò gbàgbé.+  84  Mélòó ni àwọn ọjọ́ ìránṣẹ́ rẹ?+ Ìgbà wo ni ìwọ yóò mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún lára àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi?+  85  Àwọn oníkùgbù ti wa àwọn ọ̀fìn láti mú mi,+ Àwọn tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ ti wí.+  86  Ìṣòtítọ́ ni gbogbo àṣẹ rẹ.+ Láìnídìí, wọ́n ṣe inúnibíni sí mi. Ràn mí lọ́wọ́.+  87  Díẹ̀ ló kù, wọn ì bá ti pa mí run pátápátá ní ilẹ̀ ayé;+ Ṣùgbọ́n èmi pàápàá kò fi àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ sílẹ̀.+  88  Pa mí mọ́ láàyè ní ìbámu pẹ̀lú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+ Kí n lè máa pa ìránnilétí ẹnu rẹ mọ́.+ ל [Lámédì]  89  Fún àkókò tí ó lọ kánrin, Jèhófà,+ Ọ̀rọ̀ rẹ dúró ní ọ̀run.+  90  Ìṣòtítọ́ rẹ jẹ́ fún ìran dé ìran.+ Ìwọ ti fi ilẹ̀ ayé sọlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, kí ó lè máa bá a nìṣó ní dídúró.+  91  Wọ́n dúró títí di òní,+ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ, Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ ni gbogbo wọn.+  92  Bí kì í bá ṣe pé òfin rẹ ni èmi ní ìfẹ́ni fún ni,+ Nígbà náà, èmi ì bá ti ṣègbé nínú ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́.+  93  Fún àkókò tí ó lọ kánrin, èmi kì yóò gbàgbé àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ,+ Nítorí pé o ti fi wọ́n pa mí mọ́ láàyè.+  94  Tìrẹ ni èmi. Gbà mí là,+ Nítorí pé mo ti wá àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ.+  95  Àwọn ẹni burúkú ti dúró dè mí, láti pa mí run.+ Àwọn ìránnilétí rẹ ni mo ń fiyè sí.+  96  Èmi ti rí òpin gbogbo ìjẹ́pípé.+ Àṣẹ rẹ gbòòrò gan-an. מ [Mémì]  97  Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!+ Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+  98  Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi,+ Nítorí pé tèmi ni ó jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  99  Mo ti wá ní ìjìnlẹ̀ òye ju gbogbo àwọn olùkọ́ mi,+ Nítorí pé àwọn ìránnilétí rẹ ni ìdàníyàn mi.+ 100  Èmi ń fi òye tí ó ju ti àwọn àgbà hùwà,+ Nítorí pé mo ti pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ mọ́.+ 101  Èmi ti kó ẹsẹ̀ mi ní ìjánu kúrò nínú gbogbo ipa ọ̀nà búburú,+ Kí èmi kí ó lè máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+ 102  Èmi kò yà kúrò nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ,+ Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ ti fún mi ní ìtọ́ni.+ 103  Àwọn àsọjáde rẹ mà dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in mọ́ òkè ẹnu mi o, Ó dùn ju oyin lọ lẹ́nu mi!+ 104  Nítorí àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ, mo ń fi òye hùwà.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà èké.+ נ [Núnì] 105  Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi,+ Àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.+ 106  Mo ti sọ gbólóhùn ìbúra, èmi yóò sì mú un ṣẹ dájúdájú,+ Láti máa pa àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo mọ́.+ 107  A ti ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́ púpọ̀púpọ̀.+ Jèhófà, pa mí mọ́ láàyè ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.+ 108  Jọ̀wọ́, Jèhófà, ní ìdùnnú sí àwọn ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe ti ẹnu mi,+ Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ.+ 109  Ọkàn mi wà ní àtẹ́lẹwọ́ mi nígbà gbogbo;+ Ṣùgbọ́n èmi kò gbàgbé òfin rẹ.+ 110  Àwọn ẹni burúkú ti dẹ pańpẹ́ dè mí,+ Ṣùgbọ́n èmi kò rìn gbéregbère kúrò nínú àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ.+ 111  Mo ti gba àwọn ìránnilétí rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Nítorí pé àwọn ni ayọ̀ ńláǹlà ọkàn-àyà mi.+ 112  Mo ti tẹ ọkàn-àyà mi síhà pípa àwọn ìlànà rẹ mọ́+ Fún àkókò tí ó lọ kánrin, títí dé orí èyí tí ó kẹ́yìn.+ ס [Sámékì] 113  Àwọn aláàbọ̀-ọkàn ni èmi kórìíra,+ Ṣùgbọ́n òfin rẹ ni mo nífẹ̀ẹ́.+ 114  Ìwọ ni ibi ìlùmọ́ mi àti apata mi.+ Nítorí pé ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi dúró dè.+ 115  Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,+ Kí n lè pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́.+ 116  Tì mí lẹ́yìn ní ìbámu pẹ̀lú àsọjáde rẹ, kí n lè máa wà láàyè nìṣó,+ Má sì kó ìtìjú bá mi nítorí ìrètí mi.+ 117  Gbé mi ró, kí a lè gbà mí là,+ Èmi yóò sì tẹjú mọ́ àwọn ìlànà rẹ nígbà gbogbo.+ 118  Gbogbo àwọn tí ń ṣáko lọ kúrò nínú àwọn ìlànà rẹ ni ìwọ ti fọ́n dànù;+ Nítorí pé èké ni àgálámàṣà wọn.+ 119  Gẹ́gẹ́ bí ìdàrọ́, ìwọ ti mú kí gbogbo ẹni burúkú ilẹ̀ ayé kásẹ̀ nílẹ̀.+ Nítorí náà, èmi nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí rẹ.+ 120  Nítorí ìbẹ̀rùbojo rẹ, ara mi ti sẹ́gìíìrì;+ Àti nítorí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ, àyà ti fò mí.+ ע [Áyínì] 121  Mo ti mú ìdájọ́ àti òdodo ṣẹ ní kíkún.+ Má jọ̀wọ́ mi fún àwọn tí ń lù mí ní jìbìtì!+ 122  Ṣe gẹ́gẹ́ bí onídùúró fún ìránṣẹ́ rẹ nínú ohun rere.+ Kí àwọn oníkùgbù má lù mí ní jìbìtì.+ 123  Àní ojú mi ti joro lẹ́nu wíwọ̀nà fún ìgbàlà rẹ+ Àti fún àsọjáde òdodo rẹ.+ 124  Ṣe sí ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́,+ Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìlànà tìrẹ.+ 125  Ìránṣẹ́ rẹ ni mí.+ Mú mi lóye,+ Kí n lè mọ àwọn ìránnilétí rẹ.+ 126  Ó ti tó àkókò fún Jèhófà láti gbé ìgbésẹ̀.+ Wọ́n ti rú òfin rẹ.+ 127  Ìdí nìyẹn tí mo fi nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ rẹ+ Ju wúrà, àní wúrà tí a yọ́ mọ́.+ 128  Ìdí nìyẹn tí mo fi ka gbogbo àṣẹ ìtọ́ni nípa ohun gbogbo sí èyí tí ó tọ̀nà;+ Gbogbo ipa ọ̀nà èké ni mo kórìíra.+ פ [Péè] 129  Àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ àgbàyanu.+ Ìdí nìyẹn tí ọkàn mi fi pa wọ́n mọ́.+ 130  Àní ìsọdimímọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ń fúnni ní ìmọ́lẹ̀,+ Ó ń mú kí àwọn aláìní ìrírí lóye.+ 131  Ẹnu mi ni mo ti là sílẹ̀ gbayawu, kí n lè mí hẹlẹ,+ Nítorí pé mo ti yánhànhàn fún àwọn àṣẹ rẹ.+ 132  Yí padà sọ́dọ̀ mi, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi,+ Ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu ìdájọ́ rẹ sí àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ.+ 133  Fi àwọn ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú àsọjáde rẹ,+ Kí nǹkan kan tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ má sì jẹ gàba lé mi lórí.+ 134  Tún mi rà padà kúrò lọ́wọ́ aráyé èyíkéyìí tí ń lu jìbìtì,+ Ṣe ni èmi yóò máa pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ mọ́.+ 135  Mú kí ojú rẹ tàn sára ìránṣẹ́ rẹ,+ Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+ 136  Àwọn ìṣàn omi ti ṣàn sílẹ̀ ní ojú mi+ Nítorí òtítọ́ náà pé wọn kò pa òfin rẹ mọ́.+ צ [Sádì] 137  Olódodo ni ọ́, Jèhófà,+ Àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣánṣán.+ 138  Ìwọ ti pàṣẹ àwọn ìránnilétí rẹ+ nínú òdodo Àti nínú ìṣòtítọ́ tí ó peléke.+ 139  Ìgbóná-ọkàn mi ti mú òpin bá mi,+ Nítorí pé àwọn elénìní mi ti gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ.+ 140  Àsọjáde rẹ ni a yọ́ mọ́ gidigidi,+ Ìránṣẹ́ rẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ 141  Aláìjámọ́ pàtàkì àti aláìníláárí ni mí.+ Àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ ni èmi kò gbàgbé.+ 142  Òdodo rẹ jẹ́ òdodo fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Òtítọ́ sì ni òfin rẹ.+ 143  Àní wàhálà àti ìṣòro ti wá mi rí.+ Àwọn àṣẹ rẹ ni mo ní ìfẹ́ni fún.+ 144  Òdodo àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Mú mi lóye, kí n lè máa wà láàyè nìṣó.+ ק [Kófì] 145  Mo ti fi gbogbo ọkàn-àyà mi pè.+ Dá mi lóhùn, Jèhófà.+ Àwọn ìlànà rẹ ni èmi yóò máa pa mọ́ dájúdájú.+ 146  Mo ti ké pè ọ́. Gbà mí là!+ Ṣe ni èmi yóò máa pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́.+ 147  Mo ti tètè dìde ní wíríwírí òwúrọ̀,+ kí n lè kígbe fún ìrànlọ́wọ́.+ Nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni mo dúró dè.+ 148  Ojú mi ti ṣáájú àwọn ìṣọ́ òru,+ Nítorí kí n lè fi àsọjáde rẹ ṣe ìdàníyàn mi.+ 149  Gbọ́ ohùn mi ní ìbámu pẹ̀lú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+ Jèhófà, pa mí mọ́ láàyè ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu ìdájọ́ rẹ.+ 150  Àwọn tí ń lépa ìwà àìníjàánu+ ti sún mọ́ tòsí; Wọ́n ti jìnnà réré sí òfin rẹ.+ 151  Jèhófà, ìwọ ń bẹ nítòsí,+ Òtítọ́ sì ni gbogbo àṣẹ rẹ.+ 152  Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni mo ti mọ àwọn kan lára ìránnilétí rẹ,+ Nítorí pé ìwọ ti fi ìpìlẹ̀ wọn sọlẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ ר [Réṣì] 153  Rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;+ Nítorí pé n kò gbàgbé òfin tìrẹ.+ 154  Bá mi dá ẹjọ́ mi, kí o sì mú mi padà;+ Pa mí mọ́ láàyè ní ìfohùnṣọ̀kan pẹ̀lú àsọjáde rẹ.+ 155  Ìgbàlà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú,+ Nítorí pé wọn kò wá àwọn ìlànà rẹ.+ 156  Ọ̀pọ̀ ni àánú rẹ, Jèhófà.+ Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ, pa mí mọ́ láàyè.+ 157  Àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi àti àwọn elénìní mi pọ̀.+ Èmi kò yapa kúrò nínú àwọn ìránnilétí rẹ.+ 158  Èmi ti rí àwọn aládàkàdekè nínú ìṣesí,+ Mo sì ní ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin, nítorí tí wọn kò pa àsọjáde rẹ mọ́.+ 159  Wò ó pé mo nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ ìtọ́ni tìrẹ.+ Jèhófà, pa mí mọ́ láàyè ní ìbámu pẹ̀lú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+ 160  Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ,+ Gbogbo ìpinnu ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo sì jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ ש [Sínì] tàbí [Ṣínì] 161  Àní àwọn ọmọ aládé ti ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,+ Ṣùgbọ́n ọkàn-àyà mi ní ìbẹ̀rùbojo fún ọ̀rọ̀ rẹ.+ 162  Mo ń yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí àsọjáde rẹ,+ Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti ń ṣe nígbà tí ó bá rí ohun ìfiṣèjẹ púpọ̀.+ 163  Èké ni mo kórìíra,+ mo sì ń ṣe họ́ọ̀ sí i.+ Òfin rẹ ni mo nífẹ̀ẹ́.+ 164  Ìgbà méje lóòjọ́ ni mo ń yìn ọ́+ Nítorí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo.+ 165  Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ,+ Kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.+ 166  Mo ń retí ìgbàlà rẹ, Jèhófà,+ Mo sì ti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+ 167  Ọkàn mi ti pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́,+ Mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn lọ́nà tí ó peléke.+ 168  Mo ti pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni àti àwọn ìránnilétí rẹ mọ́,+ Nítorí pé gbogbo ọ̀nà mi ń bẹ ní iwájú rẹ.+ ת [Tọ́ọ̀] 169  Kí igbe ìpàrọwà mi sún mọ́ iwájú rẹ, Jèhófà.+ Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ, mú mi lóye.+ 170  Kí ìbéèrè mi fún ojú rere wọlé wá síwájú rẹ.+ Ní ìbámu pẹ̀lú àsọjáde rẹ, dá mi nídè.+ 171  Kí ètè mi máa tú ìyìn jáde,+ Nítorí tí ìwọ ń kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+ 172  Kí ahọ́n mi máa kọrin àsọjáde rẹ,+ Nítorí pé òdodo ni gbogbo àṣẹ rẹ.+ 173  Kí ọwọ́ rẹ ràn mí lọ́wọ́,+ Nítorí pé àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ ni mo yàn.+ 174  Mo ti ń yánhànhàn fún ìgbàlà rẹ, Jèhófà,+ Òfin rẹ ni mo sì ní ìfẹ́ni fún.+ 175  Kí ọkàn mi máa wà láàyè nìṣó, kí ó sì máa yìn ọ́,+ Kí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ sì máa ràn mí lọ́wọ́.+ 176  Mo ti rìn gbéregbère bí àgùntàn tí ó sọnù.+ Wá ìránṣẹ́ rẹ,+ Nítorí pé èmi kò gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé