Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 118:1-29

118  Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere;+Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+   Kí Ísírẹ́lì sọ wàyí pé:“Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+   Kí àwọn ará ilé Áárónì sọ wàyí pé:+“Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+   Kí àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà sọ wàyí pé:+“Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+   Láti inú àwọn ipò tí ó kún fún wàhálà ni mo ti ké pe Jáà;+Jáà dá mi lóhùn, ó sì fi mí sí ibi aláyè gbígbòòrò.+   Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù.+Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?+   Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láàárín àwọn tí ń ràn mí lọ́wọ́,+Tí èmi fúnra mi yóò fi wo àwọn tí ó kórìíra mi.+   Ó sàn láti sá di Jèhófà+Ju láti gbẹ́kẹ̀ lé ará ayé.+   Ó sàn láti sá di Jèhófà+Ju láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú.+ 10  Àní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi ká.+Orúkọ Jèhófà ni mo fi ń lé wọn sẹ́yìn.+ 11  Wọ́n yí mi ká, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n rí sí i pé àwọn yí mi ká.+Orúkọ Jèhófà ni mo fi ń lé wọn sẹ́yìn. 12  Wọ́n yí mi ká bí àwọn kòkòrò oyin;+A fẹ́ wọn pa bí iná àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún.+Orúkọ Jèhófà ni mo fi ń lé wọn sẹ́yìn.+ 13  Ìwọ fi tagbára-tagbára tì mí kí n lè ṣubú,+Ṣùgbọ́n Jèhófà tìkára rẹ̀ ràn mí lọ́wọ́.+ 14  Jáà ni ibi ààbò mi àti agbára ńlá mi,+Ó sì di ìgbàlà mi.+ 15  Ohùn igbe ìdùnnú àti ìgbàlà+Ń bẹ nínú àgọ́+ àwọn olódodo.+Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń fi ìmí hàn gbangba.+ 16  Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń gbé ara rẹ̀ ga;+Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń fi ìmí hàn gbangba.+ 17  Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò máa wà láàyè nìṣó,+Kí n lè máa polongo àwọn iṣẹ́ Jáà.+ 18  Jáà tọ́ mi sọ́nà lọ́nà mímúná,+Ṣùgbọ́n kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.+ 19  Ẹ ṣí àwọn ẹnubodè òdodo fún mi.+Èmi yóò wọ inú wọn; èmi yóò gbé Jáà lárugẹ.+ 20  Èyí ni ẹnubodè Jèhófà.+Àní àwọn olódodo ni yóò wọ inú rẹ̀.+ 21  Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí tí ìwọ dá mi lóhùn,+Ìwọ sì wá di ìgbàlà mi.+ 22  Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì+Ti di olórí igun ilé.+ 23  Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá;+Ó jẹ́ àgbàyanu ní ojú wa.+ 24  Èyí ni ọjọ́ tí Jèhófà ṣe;+Àwa yóò kún fún ìdùnnú, a ó sì máa yọ̀ nínú rẹ̀.+ 25  Áà, wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́ gbani là!+Áà, wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́ yọ̀ǹda àṣeyọrí sí rere!+ 26  Ìbùkún ni fún Ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà;+Àwa ti bù kún yín láti inú ilé Jèhófà wá.+ 27  Jèhófà ni Olú Ọ̀run,+Ó sì ń fún wa ní ìmọ́lẹ̀.+Ẹ fi àwọn ẹ̀tun+ so ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn àjọyọ̀,+Títí dé ibi àwọn ìwo pẹpẹ.+ 28  Ìwọ ni Olú Ọ̀run mi, èmi yóò sì gbé ọ lárugẹ;+Ọlọ́run mi—èmi yóò gbé ọ ga.+ 29  Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere;+Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé