Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 116:1-19

116  Èmi nífẹ̀ẹ́, nítorí pé Jèhófà ń gbọ́+ Ohùn mi, àti àwọn àrọwà mi.+   Nítorí tí ó dẹ etí sí mi,+ Èmi yóò sì máa pè é jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ mi.+   Àwọn ìjàrá ikú ká mi mọ́,+ Àwọn ipò tí ó kún fún wàhálà ti Ṣìọ́ọ̀lù pàápàá sì wá mi rí.+ Wàhálà àti ẹ̀dùn-ọkàn ni mo ń rí ṣáá.+   Ṣùgbọ́n orúkọ Jèhófà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ké pè:+ “Áà, Jèhófà, pèsè àsálà fún ọkàn mi!”+   Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti olódodo;+ Ọlọ́run wa sì jẹ́ Ẹni tí ń fi àánú hàn.+   Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn aláìní ìrírí.+ Mo di òtòṣì, ó sì tẹ̀ síwájú láti gba èmi pàápàá là.+   Padà sí ibi ìsinmi rẹ, ìwọ ọkàn mi,+ Nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó bá a mu fún ọ.+   Nítorí pé ìwọ ti gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú,+ O ti gba ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, o ti gba ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìkọ̀sẹ̀.+   Ṣe ni èmi yóò máa rìn+ níwájú Jèhófà ní ilẹ̀ àwọn alààyè.+ 10  Mo ní ìgbàgbọ́,+ nítorí tí mo bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀.+ Èmi pàápàá ni a ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ gidigidi. 11  Èmi, ní tèmi, wí, nígbà tí ẹ̀rù jìnnìjìnnì bò mí,+ pé: “Òpùrọ́ ni gbogbo ènìyàn.”+ 12  Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà+ Nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?+ 13  Ife ìgbàlà títóbi lọ́lá+ ni èmi yóò gbé, Orúkọ Jèhófà ni èmi yóò sì máa ké pè.+ 14  Àwọn ẹ̀jẹ́ mi ni èmi yóò san fún Jèhófà,+ Bẹ́ẹ̀ ni, ní iwájú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀. 15  Iyebíye ní ojú Jèhófà Ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.+ 16  Áà, wàyí o, Jèhófà,+ Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni èmi.+ Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, ọmọ ẹrúbìnrin rẹ.+ Ìwọ ti tú àwọn ìdè mi.+ 17  Ìwọ ni èmi yóò rú ẹbọ ìdúpẹ́ sí,+ Orúkọ Jèhófà ni èmi yóò sì máa ké pè.+ 18  Àwọn ẹ̀jẹ́ mi ni èmi yóò san fún Jèhófà,+ Bẹ́ẹ̀ ni, ní iwájú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,+ 19  Nínú àwọn àgbàlá ilé Jèhófà,+ Láàárín rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.+ Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé