Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 115:1-18

115  Kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ tiwa, Jèhófà, kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ tiwa,+Bí kò ṣe láti máa fi ògo fún orúkọ rẹ+Ní ìbámu pẹ̀lú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, ní ìbámu pẹ̀lú òótọ́ rẹ.+   Èé ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi sọ pé:+“Wàyí o, Ọlọ́run wọn dà?”+   Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa ń bẹ ní ọ̀run;+Ohun gbogbo tí ó ní inú dídùn sí láti ṣe ni ó ti ṣe.+   Àwọn òrìṣà wọn jẹ́ fàdákà àti wúrà,+Iṣẹ́ ọwọ́ ará ayé.+   Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀;+Wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè ríran;+   Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbọ́ran.+Wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbóòórùn.+   Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lè fọwọ́ ba nǹkan.+Wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè rìn;+Wọn kì í mú ìró kankan jáde láti ọ̀fun wọn.+   Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóò dà bí àwọn gan-an,+Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+   Ísírẹ́lì, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+Òun ni ìrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.+ 10  Ilé Áárónì, ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+Òun ni ìrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.+ 11  Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+Òun ni ìrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.+ 12  Jèhófà tìkára rẹ̀ ti rántí wa; òun yóò bù kún wa,+Yóò bù kún ilé Ísírẹ́lì,+Yóò bù kún ilé Áárónì.+ 13  Òun yóò bù kún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà,+Àwọn ẹni kékeré àti àwọn ẹni ńlá.+ 14  Jèhófà yóò mú yín pọ̀ sí i,+Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín.+ 15  Ẹ̀yin ni alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà,+Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.+ 16  Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run,+Ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.+ 17  Àwọn òkú kì í yin Jáà,+Tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́.+ 18  Ṣùgbọ́n àwa fúnra wa yóò máa fi ìbùkún fún Jáà+Láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.+Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé