Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 114:1-8

114  Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde lọ kúrò ní Íjíbítì,+Tí ilé Jékọ́bù jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò yéni,+   Júdà di ibi mímọ́ rẹ̀,+Ísírẹ́lì di àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀ títóbi lọ́lá.+   Àní òkun rí i, ó sì fẹsẹ̀ fẹ;+Ní ti Jọ́dánì, ó bẹ̀rẹ̀ sí yí padà.+   Àní àwọn òkè ńlá ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àwọn àgbò,+Àti àwọn òkè kéékèèké bí àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn.   Kí ní ṣe ọ́, ìwọ òkun, tí o fi fẹsẹ̀ fẹ,+Ìwọ Jọ́dánì, tí o fi bẹ̀rẹ̀ sí yí padà?+   Ẹ̀yin òkè ńláńlá, tí ẹ fi ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àwọn àgbò;+Àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn?+   Ìwọ ilẹ̀ ayé, jẹ ìrora mímúná nítorí Olúwa,+Nítorí Ọlọ́run Jékọ́bù,   Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi tí ó kún fún esùsú,+Tí ó sọ akọ àpáta di ìsun omi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé