Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 113:1-9

113  Ẹ yin Jáà!+Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,+Ẹ máa yin orúkọ Jèhófà.+   Kí orúkọ Jèhófà di èyí tí a fi ìbùkún fún+Láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.+   Láti yíyọ oòrùn títí di ìgbà wíwọ̀ rẹ̀,+Orúkọ Jèhófà yẹ fún ìyìn.+   Jèhófà ga lékè gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;+Ògo rẹ̀ lékè ọ̀run.+   Ta ní dà bí Jèhófà Ọlọ́run wa,+Ẹni tí ó fi ibi gíga lókè ṣe ibùgbé rẹ̀?+   Ó ń rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ láti wo ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,+   Ó ń gbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde àní láti inú ekuru;+Ó ń gbé òtòṣì ga àní láti inú kòtò eérú,+   Láti mú kí ó bá àwọn ọ̀tọ̀kùlú jókòó,+Àwọn ọ̀tọ̀kùlú lára àwọn ènìyàn rẹ̀.+   Ó ń mú kí àgàn máa gbé inú ilé+Gẹ́gẹ́ bí onídùnnú ìyá àwọn ọmọ.+Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé