Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 112:1-10

112  Ẹ yin Jáà!+ א [Áléfì]Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà,+ב [Bétì]Tí ó ní inú dídùn+ gidigidi sí àwọn àṣẹ rẹ̀.+ ג [Gímélì]   Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò di alágbára ńlá ní ilẹ̀ ayé.+ ד [Dálétì]Ní ti ìran àwọn adúróṣánṣán, yóò ní ìbùkún.+ ה [Híì]   Àwọn ohun tí ó níye lórí àti ọrọ̀ wà nínú ilé rẹ̀;+ו [Wọ́ọ̀]Òdodo rẹ̀ sì dúró títí láé.+ ז [Sáyínì]   Ó ti kọ mànà nínú òkùnkùn gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ fún àwọn adúróṣánṣán.+ ח [Kétì]Òun jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti olódodo.+ ט [Tétì]   Ènìyàn rere ni ẹni tí ń fi oore ọ̀fẹ́ hàn,+ tí ó sì ń wínni.+ י [Yódì]Ó ń fi ìdájọ́ òdodo gbé àwọn àlámọ̀rí rẹ̀ ró.+ כ [Káfì]   Nítorí a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n ní àkókò kankan.+ ל [Lámédì]Olódodo yóò wà fún ìrántí fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ מ [Mémì]   Kì yóò fòyà ìhìn búburú pàápàá.+ נ [Núnì]Ọkàn-àyà rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,+ a gbé e lé Jèhófà.+ ס [Sámékì]   Ọkàn-àyà rẹ̀ jẹ́ aláìṣeémì;+ òun kì yóò fòyà,+ע [Áyínì]Títí yóò fi máa wo àwọn elénìní rẹ̀.+ פ [Péè]   Ó ti pín nǹkan fúnni lọ́nà gbígbòòrò; ó ti fún àwọn òtòṣì.+ צ [Sádì]Òdodo rẹ̀ dúró títí láé.+ ק [Kófì]A ó fi ògo gbé ìwo rẹ̀ ga.+ ר [Réṣì] 10  Àní ẹni burúkú yóò rí i, yóò sì bínú dájúdájú.+ ש [Ṣínì]Àní yóò wa eyín pọ̀, yóò sì yọ́ dànù ní ti gidi.+ ת [Tọ́ọ̀]Ìfẹ́-ọkàn àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé