Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 111:1-10

111  Ẹ yin Jáà!+ א [Áléfì]Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé Jèhófà lárugẹ+ב [Bétì]Nínú àwùjọ tímọ́tímọ́+ ti àwọn adúróṣánṣán àti ti àpéjọ.+ ג [Gímélì]   Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tóbi,+ד [Dálétì]Wíwá kiri ni wọ́n jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ó ní inú dídùn sí wọn.+ ה [Híì]   Ìgbòkègbodò rẹ̀+ jẹ́ iyì àti ọlá ńlá pàápàá,+ו [Wọ́ọ̀]Òdodo rẹ̀ sì dúró títí láé.+ ז [Sáyínì]   Ó ti ṣe ìrántí fún àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+ ח [Kétì]Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú.+ ט [Tétì]   Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.+ י [Yódì]Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni òun yóò máa rántí májẹ̀mú rẹ̀.+ כ [Káfì]   Ó ti sọ agbára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀,+ל [Lámédì]Ní fífún wọn ní ogún àwọn orílẹ̀-èdè.+ מ [Mémì]   Òtítọ́ àti ìdájọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+נ [Núnì]Aṣeégbẹ́kẹ̀lé ni gbogbo àṣẹ ìtọ́ni tí ó ń fi fúnni,+ ס [Sámékì]   Èyí tí a tì lẹ́yìn dáadáa títí láé, fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ע [Áyínì]Tí a ṣe nínú òtítọ́ àti ìdúróṣánṣán.+ פ [Péè]   Ìtúnràpadà ni òun ti fi ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn rẹ̀,+ צ [Sádì]Ó ti pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ ק [Kófì]Mímọ́ àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ni orúkọ rẹ̀.+ ר [Réṣì] 10  Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n.+ ש [Sínì]Gbogbo àwọn tí ń pa wọ́n mọ́ ní ìjìnlẹ̀ òye rere.+ ת [Tọ́ọ̀]Ìyìn rẹ̀ dúró títí láé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé