Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 110:1-7

Ti Dáfídì. Orin atunilára. 110  Àsọjáde Jèhófà fún Olúwa mi ni pé:+“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,+Títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.”+   Ọ̀pá+ okun rẹ ni Jèhófà yóò rán jáde láti Síónì,+ pé:“Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.”+   Àwọn ènìyàn rẹ+ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn+ ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ.+Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́,+ láti inú ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀,Ìwọ ní àwùjọ rẹ ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tí ń sẹ̀.+   Jèhófà ti búra+ (kì yóò sì pèrò dà)+ pé:“Ìwọ jẹ́ àlùfáà fún àkókò tí ó lọ kánrin+Ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì!”+   Jèhófà tìkára rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ+Yóò fọ́ àwọn ọba sí wẹ́wẹ́ dájúdájú ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.+   Òun yóò mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;+Òun yóò ṣokùnfa ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn òkú.+Ṣe ni òun yóò fọ́ orí ẹni tí í ṣe olórí ilẹ̀ elénìyàn púpọ̀ sí wẹ́wẹ́.+   Àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ń bẹ ní ọ̀nà ni òun yóò ti mu.+Ìdí nìyẹn tí òun yóò fi gbé orí rẹ̀ ga sókè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé