Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 11:1-7

Sí olùdarí. Ti Dáfídì. 11  Mo ti sá di Jèhófà.+Kí ló mú yín dá a láṣà láti sọ fún ọkàn mi pé:“Sá bí ẹyẹ lọ sí òkè ńlá yín!+   Nítorí, wò ó! àwọn ẹni burúkú tìkára wọn fa ọrun,+Wọ́n ti múra ọfà wọn sílẹ̀ lára okùn ọrun,Láti ta á nínú ìṣúdùdù, sí àwọn adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.+   Nígbà tí a ya àwọn ìpìlẹ̀ pàápàá lulẹ̀,+Kí ni kí olódodo ṣe?”   Jèhófà ń bẹ nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.+Jèhófà—ọ̀run ni ìtẹ́ rẹ̀.+Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ títàn yanran ń ṣàyẹ̀wò+ àwọn ọmọ ènìyàn.   Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú,+Dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.+   Òun yóò rọ̀jò pańpẹ́, iná àti imí ọjọ́+ sórí àwọn ẹni burúkúÀti ẹ̀fúùfù tí ń jóni gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín ife wọn.+   Nítorí olódodo ni Jèhófà;+ ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìṣe òdodo.+Àwọn adúróṣánṣán ni yóò rí ojú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé