Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 109:1-31

Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin atunilára. 109  Ìwọ Ọlọ́run ìyìn mi,+ má ṣe dákẹ́.+   Nítorí pé ẹnu ẹni burúkú àti ẹnu ẹ̀tàn ti là sí mi.+Wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ nípa mi;+   Wọ́n sì ti fi ọ̀rọ̀ ìkórìíra yí mi ká,+Wọ́n sì ń bá mi jà láìnídìí.+   Nítorí ìfẹ́ mi, wọ́n ń takò mí ṣáá;+Ṣùgbọ́n níhà ọ̀dọ̀ mi, àdúrà ń bẹ.+   Wọ́n sì ń fi ibi san rere fún mi+Àti ìkórìíra fún ìfẹ́ mi.+   Yan ẹni burúkú lé e lórí,Kí alátakò+ pàápàá sì dúró pa sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.   Nígbà tí a bá ṣèdájọ́ rẹ̀, kí ó jáde lọ ní ẹni burúkú;Kí àdúrà rẹ̀ pàápàá sì di ẹ̀ṣẹ̀.+   Kí àwọn ọjọ́ rẹ̀ kéré níye;+Kí ẹlòmíràn gba ipò iṣẹ́ àbójútó rẹ̀.+   Kí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ di ọmọdékùnrin aláìníbaba,+Kí aya rẹ̀ sì di opó.+ 10  Láìkùnà, kí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa rìn gbéregbère kiri;+Kí wọ́n sì máa tọrọ,Kí wọ́n sì máa wá oúnjẹ láti àwọn ibi ahoro wọn.+ 11  Kí agbẹ̀dá-owó dẹ pańpẹ́ sílẹ̀ de gbogbo ohun tí ó ní,+Kí àwọn àjèjì+ sì piyẹ́ àmújáde làálàá rẹ̀.+ 12  Kí ó má ṣe ní ẹnikẹ́ni tí yóò nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí i,+Kí ó má sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò fi ojú rere hàn sí àwọn ọmọdékùnrin rẹ̀ aláìníbaba. 13  Kí ìran àtẹ̀lé tí ó jẹ́ tirẹ̀ wà fún ìkékúrò.+Kí a nu orúkọ wọn kúrò ní ìran tí yóò tẹ̀ lé e.+ 14  Kí a rántí ìṣìnà àwọn baba ńlá rẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà,+Àti ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀+—kí a má nù ún kúrò.+ 15  Kí wọ́n máa wà ní iwájú Jèhófà nígbà gbogbo;+Kí òun sì ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé pàápàá;+ 16  Nítorí ìdí náà pé kò rántí láti ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́,+Ṣùgbọ́n ó ń lépa ènìyàn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì+Àti oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà, láti fi ikú pa á.+ 17  Ó sì ń nífẹ̀ẹ́ ìfiré,+ tí ó fi wá sórí rẹ̀;+Kò sì ní inú dídùn sí ìbùkún,+Tí ó fi jìnnà réré sí i;+ 18  Ó sì wọ ìfiré gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù rẹ̀.+Tí ó fi wá bí omi sínú rẹ̀+Àti bí òróró sínú egungun rẹ̀. 19  Kí ó wà fún un bí ẹ̀wù tí ó fi ń bo ara rẹ̀+Àti gẹ́gẹ́ bí àmùrè tí ó fi ń di ara rẹ̀ nígbà gbogbo.+ 20  Èyí ni owó ọ̀yà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fún ẹni tí ń takò mí+Àti fún àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.+ 21  Ṣùgbọ́n ìwọ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+Bá mi lò nítorí orúkọ rẹ.+Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ dára, dá mi nídè.+ 22  Nítorí pé ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí,+Ọkàn-àyà mi pàápàá ni a sì ti gún nínú mi.+ 23  Bí òjìji nígbà tí ó bá ń pa rẹ́ lọ, a sọ ọ́ di dandan fún mi láti lọ;+A ti gbọ̀n mí dànù bí eéṣú. 24  Àwọn eékún mi pàápàá ti yẹ̀ nítorí ààwẹ̀ gbígbà,+Ẹran ara mi sì ti rù, láìní òróró kankan.+ 25  Èmi pàápàá sì ti di ohun ẹ̀gàn lójú wọn.+Wọ́n rí mi—wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí mi orí wọn.+ 26  Ràn mí lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi;+Gbà mí là ní ìbámu pẹ̀lú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.+ 27  Kí wọ́n sì mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí;+Pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, ni ó ṣe é.+ 28  Kí àwọn, ní tiwọn, máa kéde ìfiré,+Ṣùgbọ́n kí ìwọ, ní tìrẹ, máa súre.+Wọ́n ti dìde, ṣùgbọ́n kí ojú tì wọ́n,+Kí ìránṣẹ́ rẹ sì máa yọ̀.+ 29  Kí a fi ìtẹ́lógo wọ àwọn tí ń takò mí,+Kí wọ́n sì fi ìtìjú wọn bora bí ẹní fi aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá bora.+ 30  Èmi yóò fi ẹnu mi gbé Jèhófà lárugẹ gidigidi,+Èmi yóò sì máa yìn ín láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.+ 31  Nítorí tí òun yóò dúró ní ọwọ́ ọ̀tún òtòṣì,+Láti gbà á là lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣèdájọ́ ọkàn rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé