Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 108:1-13

Orin. Orin atunilára ti Dáfídì. 108  Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, Ọlọ́run.+Ṣe ni èmi yóò máa kọrin, tí èmi yóò sì máa kọ orin atunilára,+Àní pẹ̀lú ògo mi.+   Jí, ìwọ ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù.+Ṣe ni èmi yóò jí ọ̀yẹ̀.+   Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ láàárín àwọn ènìyàn, Jèhófà;+Èmi yóò sì máa kọ orin atunilára sí ọ láàárín àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.+   Nítorí tí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ga títí dé ọ̀run,+Àti òótọ́ rẹ títí dé sánmà.+   Kí a gbé ọ ga lékè ọ̀run, Ọlọ́run;+Kí ògo rẹ sì wà lókè gbogbo ilẹ̀ ayé.+   Kí a lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ ọ̀wọ́n sílẹ̀,+Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá mi lóhùn.+   Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ pé:+“Ṣe ni èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, ṣe ni èmi yóò fi Ṣékémù+ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìpín;+Èmi yóò sì díwọ̀n pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Súkótù.+   Gílíádì+ jẹ́ tèmi; Mánásè+ jẹ́ tèmi;Éfúráímù sì ni odi agbára ẹni tí mo fi ṣe olórí;+Júdà ni ọ̀pá àṣẹ mi.+   Móábù+ ni ìkòkò tí mo fi ń fọ nǹkan.+Orí Édómù+ ni èmi yóò sọ sálúbàtà mi sí.+Lórí Filísíà+ ni èmi yóò kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun.”+ 10  Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú ńlá olódi?+Ta ni yóò ṣamọ̀nà mi ní ti tòótọ́ títí dé Édómù?+ 11  Kì í ha ṣe ìwọ, Ọlọ́run, ẹni tí ó ti ta wá nù,+Tí kò sì bá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa jáde lọ bí Ọlọ́run?+ 12  Fún wa ní ìrànwọ́ kúrò lọ́wọ́ wàhálà,+Níwọ̀n bí ìgbàlà nípasẹ̀ ará ayé kò ti ní láárí.+ 13  Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa yóò jèrè ìmí,+Òun fúnra rẹ̀ yóò sì tẹ àwọn elénìní wa mọ́lẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé