Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 107:1-43

(Sáàmù 107 sí 150) 107  Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere;+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+   Kí àwọn ẹni tí Jèhófà gbà padà sọ bẹ́ẹ̀,+ Àwọn tí ó gbà padà lọ́wọ́ elénìní,+   Àwọn tí ó sì ti kó jọ pa pọ̀ àní láti àwọn ilẹ̀,+ Láti yíyọ oòrùn àti láti wíwọ̀ oòrùn,+ Láti àríwá àti láti gúúsù.+   Wọ́n rìn káàkiri ní aginjù,+ ní aṣálẹ̀;+ Wọn kò rí ọ̀nà èyíkéyìí sí ìlú ńlá tí ó jẹ́ ibi gbígbé.+   Ebi pa wọ́n, òùngbẹ sì gbẹ wọ́n pẹ̀lú;+ Àní àárẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mú ọkàn wọn nínú wọn.+   Wọ́n sì ń ké jáde ṣáá sí Jèhófà nínú wàhálà wọn;+ Ó tẹ̀ síwájú láti dá wọn nídè kúrò nínú másùnmáwo tí ó dé bá wọn,+   Àti láti mú kí wọ́n rìn ní ọ̀nà tí ó tọ́,+ Kí wọ́n bàa lè wá sí ìlú ńlá tí ó jẹ́ ibi gbígbé.+   Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́+ Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.+   Nítorí pé ó ti tẹ́ ọkàn gbígbẹ táútáú lọ́rùn;+ Ó sì ti fi ohun rere kún ọkàn tí ebi ń pa.+ 10  Àwọn kan ń bẹ tí ń gbé inú òkùnkùn àti ibú òjìji,+ Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń bẹ nínú ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́ àti irin.+ 11  Nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀+ sí àwọn àsọjáde Ọlọ́run;+ Ìmọ̀ràn Ẹni Gíga Jù Lọ ni wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún.+ 12  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ìdààmú tẹ ọkàn-àyà wọn ba;+ Wọ́n kọsẹ̀, kò sì sí ẹni tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́.+ 13  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nínú wàhálà wọn;+ Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó gbà wọ́n là kúrò nínú másùnmáwo tí ó dé bá wọn.+ 14  Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti ibú òjìji,+ Ó sì fa ọ̀já wọn pàápàá já.+ 15  Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́+ Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.+ 16  Nítorí pé ó ti fọ́ àwọn ilẹ̀kùn bàbà,+ Àní ó ti ké àwọn ọ̀pá ìdábùú tí a fi irin ṣe lulẹ̀.+ 17  Àwọn tí ó ya òmùgọ̀, nítorí ọ̀nà ìrélànàkọjá wọn+ Àti nítorí ìṣìnà wọn, wọ́n ṣẹ́ ara wọn níṣẹ̀ẹ́ níkẹyìn.+ 18  Ọkàn wọn ṣe họ́ọ̀ sí gbogbo onírúurú oúnjẹ pàápàá,+ Wọ́n sì dé àwọn ẹnubodè ikú.+ 19  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nínú wàhálà wọn;+ Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó gbà wọ́n là kúrò nínú másùnmáwo tí ó dé bá wọn.+ 20  Ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ránṣẹ́, ó sì mú wọn lára dá,+ Ó sì pèsè àsálà fún wọn kúrò nínú kòtò wọn.+ 21  Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́+ Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.+ 22  Kí wọ́n sì máa rú ẹbọ ìdúpẹ́,+ Kí wọ́n sì máa fi igbe ìdùnnú polongo àwọn iṣẹ́ rẹ̀.+ 23  Àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí òkun nínú àwọn ọkọ̀,+ Àwọn tí ń ṣòwò lórí alagbalúgbú omi,+ 24  Àwọn ni ó ti rí àwọn iṣẹ́ Jèhófà+ Àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ nínú ibú;+ 25  Bí ó ti sọ ọ̀rọ̀, tí ó sì mú kí ẹ̀fúùfù oníjì líle dìde,+ Tí ó fi jẹ́ pé ó gbé ìgbì rẹ̀ sókè.+ 26  Wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run, Wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀. Nítorí ìyọnu àjálù, àní ọkàn wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí domi.+ 27  Wọ́n ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, wọ́n sì ń rìn tàgétàgé bí ọ̀mùtípara,+ Àní gbogbo ọgbọ́n wọ́n já sí ìdàrúdàpọ̀.+ 28  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà nínú wàhálà wọn,+ Ó sì mú wọn jáde wá láti inú másùnmáwo tí ó dé bá wọn.+ 29  Ó mú kí ìjì ẹlẹ́fùúùfù dúró ní píparọ́rọ́,+ Tí ó fi jẹ́ pé ìgbì òkun dákẹ́ jẹ́ẹ́.+ 30  Wọ́n sì yọ̀ nítorí pé ìwọ̀nyí pa rọ́rọ́, Ó sì ṣamọ̀nà wọn lọ sí ibi èbúté tí wọ́n ní inú dídùn sí.+ 31  Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́+ Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.+ 32  Kí wọ́n sì máa kókìkí rẹ̀ nínú ìjọ àwọn ènìyàn;+ Kí wọ́n sì máa yìn ín níbi ìjókòó àwọn àgbàlagbà.+ 33  Ó ń yí àwọn odò padà di aginjù,+ Àti ìṣànjáde omi di ìyàngbẹ ilẹ̀,+ 34  Ilẹ̀ eléso di ilẹ̀ iyọ̀,+ Nítorí ìwà búburú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. 35  Ó ń yí aginjù padà di adágún omi tí ó kún fún esùsú,+ Àti ilẹ̀ tí ó jẹ́ ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi di ibi tí omi ti ń ṣàn jáde.+ 36  Ó sì ń mú kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé níbẹ̀,+ Kí wọ́n bàa lè fìdí ìlú ńlá tí ó jẹ́ ibi gbígbé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ 37  Wọ́n sì fúnrúgbìn sí àwọn pápá, wọ́n sì gbin àwọn ọgbà àjàrà,+ Kí wọ́n lè so àwọn irè oko eléso.+ 38  Ó sì súre fún wọn tí ó fi jẹ́ pé wọ́n di púpọ̀ gidigidi;+ Kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n kéré níye.+ 39  Wọ́n tún kéré níye sí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀+ Nítorí ìkálọ́wọ́kò, ìyọnu àjálù àti ẹ̀dùn-ọkàn.+ 40  Ó ń tú ìfojú-tín-ín-rín dà sórí àwọn ọ̀tọ̀kùlú,+ Tí ó fi jẹ́ pé ó ń mú kí wọ́n rìn gbéregbère ní ibi júujùu, níbi tí ọ̀nà kò sí.+ 41  Ṣùgbọ́n ó ń dáàbò bo òtòṣì kúrò lọ́wọ́ ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́,+ Ó sì ń yí i padà di àwọn ìdílé gẹ́gẹ́ bí agbo ẹran kan.+ 42  Àwọn adúróṣánṣán rí èyí, wọ́n sì yọ̀;+ Ṣùgbọ́n ní ti gbogbo àìṣòdodo, ó ní láti pa ẹnu rẹ̀ dé.+ 43  Ta ni ó gbọ́n? Yóò kíyè sí nǹkan wọ̀nyí,+ Yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní olùfiyèsí àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé