Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 106:1-48

106  Ẹ yin Jáà!+ Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere;+ Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+   Ta ní lè sọ àwọn iṣẹ́ agbára ńlá Jèhófà jáde,+ Tàbí tí ó lè mú kí a gbọ́ gbogbo ìyìn rẹ̀?+   Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa ìdájọ́ òdodo mọ́,+ Àwọn tí ń ṣe òdodo ní gbogbo ìgbà.+   Jèhófà, fi ìfẹ́ rere rẹ sí àwọn ènìyàn rẹ rántí mi.+ Fi ìgbàlà rẹ tọ́jú mi,+   Kí n lè rí oore tí a ṣe sí àwọn àyànfẹ́ rẹ,+ Kí n lè máa yọ̀ nínú ayọ̀ yíyọ̀ orílẹ̀-èdè rẹ,+ Kí n lè máa ṣògo pẹ̀lú ogún rẹ.+   Àwa ti ṣẹ̀ bí ti àwọn baba ńlá wa;+ Àwa ti ṣe àìtọ́; àwa ti ṣe burúkú.+   Ní ti àwọn baba ńlá wa ní Íjíbítì, Wọn kò fi ìjìnlẹ̀ òye kankan hàn nínú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+ Wọn kò rántí ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ tí ó tóbi lọ́lá,+ Ṣùgbọ́n wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ní òkun, lẹ́bàá Òkun Pupa.+   Ó sì tẹ̀ síwájú láti gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ̀,+ Kí ó lè sọ agbára ńlá rẹ̀ di mímọ̀.+   Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó bá Òkun Pupa wí lọ́nà mímúná, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó gbẹ táútáú;+ Ó sì mú wọn rìn gba ibú omi kọjá bí ẹní gba aginjù kọjá;+ 10  Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà wọ́n là lọ́wọ́ olùkórìíra,+ Ó sì tún wọn gbà padà lọ́wọ́ ọ̀tá.+ 11  Omi sì bo àwọn elénìní wọn;+ Ìkankan lára wọn kò ṣẹ́ kù.+ 12  Nígbà náà ni wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀;+ Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn rẹ̀.+ 13  Kíákíá ni wọ́n gbàgbé àwọn iṣẹ́ rẹ̀;+ Wọn kò dúró de ìmọ̀ràn rẹ̀.+ 14  Ṣùgbọ́n wọ́n fi ìfẹ́-ọkàn onímọtara-ẹni-nìkan wọn hàn ní aginjù,+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dán Ọlọ́run wò ní aṣálẹ̀.+ 15  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè,+ Ó sì rán òkùnrùn amúnijoro sínú ọkàn wọn.+ 16  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara Mósè ní ibùdó,+ Àní Áárónì, ẹni mímọ́ Jèhófà.+ 17  Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, ó sì gbé Dátánì mì,+ Ó sì bo àpéjọ Ábírámù mọ́lẹ̀.+ 18  Iná kan sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ní àpéjọ wọn;+ Àní ọwọ́ iná kan bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn ẹni burúkú run.+ 19  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n ṣe ọmọ màlúù kan ní Hórébù,+ Wọ́n sì tẹrí ba fún ère dídà,+ 20  Tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ṣe pàṣípààrọ̀ ògo mi+ Pẹ̀lú àwòrán akọ màlúù, tí í ṣe olùjẹ ewéko.+ 21  Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà wọn,+ Olùṣe àwọn ohun ńlá ní Íjíbítì,+ 22  Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu ní ilẹ̀ Hámù,+ Àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù ní Òkun Pupa.+ 23  Díẹ̀ ló kù kí ó sọ pé kí a pa wọ́n rẹ́ ráúráú,+ Ọpẹ́lọpẹ́ Mósè àyànfẹ́ rẹ̀, Tí ó dúró sí àlàfo tí ń bẹ níwájú rẹ̀,+ Láti yí ìhónú rẹ̀ padà, kí ó má bàa run wọ́n.+ 24  Wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú ilẹ̀ fífani-lọ́kàn-mọ́ra náà;+ Wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 25  Wọ́n sì ń ráhùn ṣáá nínú àgọ́ wọn;+ Wọn kò fetí sí ohùn Jèhófà.+ 26  Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè nínú ìbúra nípa wọn,+ Pé òun yóò mú kí wọ́n ṣubú ní aginjù,+ 27  Àti pé òun yóò mú kí àwọn ọmọ wọn ṣubú láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ Àti pé òun yóò tú wọn ká sáàárín àwọn ilẹ̀.+ 28  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí so ara wọn mọ́ Báálì ti Péórù,+ Wọ́n sì ń jẹ ẹbọ òkú.+ 29  Bí wọ́n ti ń ṣokùnfà ìmúnibínú nípasẹ̀ àwọn ìbálò wọn,+ Òjòjò àrànkálẹ̀ bẹ́ sílẹ̀ wàyí láàárín wọn.+ 30  Nígbà tí Fíníhásì dìde, tí ó sì dá sí i,+ Nígbà náà ni òjòjò àrànkálẹ̀ náà dáwọ́ dúró. 31  A sì wá kà á sí òdodo fún un Ní ìran dé ìran fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 32  Síwájú sí i, wọ́n fa ìtánni-ní-sùúrù níbi omi Mẹ́ríbà,+ Tí ó fi jẹ́ pé nǹkan burú fún Mósè nítorí wọn.+ 33  Nítorí pé wọ́n mú ẹ̀mí rẹ̀ korò, Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ètè rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà ìwàǹwára.+ 34  Wọn kò pa àwọn ènìyàn náà rẹ́ ráúráú,+ Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún wọn.+ 35  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,+ Wọ́n sì ń kọ́ àwọn iṣẹ́ wọn.+ 36  Wọ́n sì ń sin òrìṣà wọn,+ Ìwọ̀nyí sì wá jẹ́ ìdẹkùn fún wọn.+ 37  Wọn a sì máa fi àwọn ọmọkùnrin wọn+ Àti àwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù.+ 38  Tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀ ṣáá,+ Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọn, Àwọn tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà Kénáánì;+ Ìtàjẹ̀sílẹ̀ sì wá sọ ilẹ̀ náà di eléèérí.+ 39  Wọ́n sì wá di aláìmọ́ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ wọn,+ Wọ́n sì ń ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe nípasẹ̀ àwọn ìbálò wọn.+ 40  Ìbínú Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sí àwọn ènìyàn rẹ̀,+ Ó sì wá ṣe họ́ọ̀ sí ogún rẹ̀.+ 41  Léraléra ni ó sì fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,+ Kí àwọn tí ó kórìíra wọn lè ṣàkóso lé wọn lórí,+ 42  Kí àwọn ọ̀tá wọn sì lè ni wọ́n lára, Kí a sì tẹ̀ wọ́n lórí ba lábẹ́ ọwọ́ wọn.+ 43  Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dá wọn nídè,+ Ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn a ṣọ̀tẹ̀ nínú ipa ọ̀nà àìgbọràn wọn,+ A sì rẹ̀ wọ́n wálẹ̀ nítorí ìṣìnà wọn.+ 44  Òun a sì rí wàhálà wọn+ Nígbà tí ó bá gbọ́ igbe ìpàrọwà wọn.+ 45  Òun a sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ sí wọn,+ Òun a sì kẹ́dùn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tí ó tóbi lọ́lá.+ 46  Òun a sì jẹ́ kí wọ́n di ẹni ìṣojú-àánú-sí Níwájú gbogbo àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè.+ 47  Gbà wá là, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa,+ Kí o sì kó wa jọpọ̀ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè,+ Kí a lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,+ Kí a lè máa fi ayọ̀ ńláǹlà sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ.+ 48  Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ Láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin; Kí gbogbo ènìyàn sì wí pé Àmín.+ Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé