Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 105:1-45

105  Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,+Ẹ sọ àwọn ìbálò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn.+   Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin atunilára sí i,+Ẹ máa fi gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ ṣe ìdàníyàn yín.+   Ẹ máa ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀.+Kí ọkàn-àyà àwọn tí ń wá Jèhófà máa yọ̀.+   Ẹ máa wá Jèhófà àti okun rẹ̀.+Ẹ máa wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.+   Ẹ máa rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ tí ó ti ṣe,+Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ ẹnu rẹ̀,+   Ẹ̀yin irú-ọmọ Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀,+Ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ̀yin àyànfẹ́ rẹ̀.+   Òun ni Jèhófà Ọlọ́run wa.+Àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ilẹ̀ ayé.+   Ó ti rántí májẹ̀mú rẹ̀ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin,+Ọ̀rọ̀ tí ó pa láṣẹ, títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+   Májẹ̀mú tí ó bá Ábúráhámù dá,+Àti gbólóhùn ìbúra rẹ̀ fún Ísákì,+ 10  Àti gbólóhùn tí ó mú kí ó máa dúró nìṣó gẹ́gẹ́ bí ìlànà àní fún Jékọ́bù,Gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin àní fún Ísírẹ́lì,+ 11  Pé: “Ìwọ ni èmi yóò fi ilẹ̀ Kénáánì fún+Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìpín ogún yín.”+ 12  Èyí jẹ́ nígbà tí wọ́n kéré níye,+Bẹ́ẹ̀ ni, tí wọ́n kéré níye gan-an, tí wọ́n sì jẹ́ àtìpó nínú rẹ̀.+ 13  Wọ́n sì ń rìn káàkiri ṣáá láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,+Láti ọ̀dọ̀ ìjọba kan dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn.+ 14  Kò gba ẹ̀dá ènìyàn kankan láyè láti lù wọ́n ní jìbìtì,+Ṣùgbọ́n ó fi ìbáwí tọ́ àwọn ọba sọ́nà ní tìtorí wọn,+ 15  Pé: “Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,+Ẹ má sì ṣe ohun búburú kankan sí àwọn wòlíì mi.”+ 16  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà;+Ó ṣẹ́ gbogbo ọ̀pá tí a fi àwọn ìṣù búrẹ́dì onírìísí òrùka rọ̀ sí.+ 17  Ó rán ọkùnrin kan lọ ṣáájú wọn,Jósẹ́fù, ẹni tí a tà láti jẹ́ ẹrú.+ 18  Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́,+Ọkàn rẹ̀ wá sínú àwọn irin;+ 19  Títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dé,+Àsọjáde Jèhófà tìkára rẹ̀ yọ́ ọ mọ́.+ 20  Ọba ránṣẹ́ kí òun bàa lè tú u sílẹ̀,+Àní olùṣàkóso àwọn ènìyàn ránṣẹ́, kí òun bàa lè jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lọ. 21  Ó fi í ṣe ọ̀gá agbo ilé rẹ̀+Àti olùṣàkóso lórí gbogbo dúkìá rẹ̀,+ 22  Kí ó lè de àwọn ọmọ aládé rẹ̀ lọ́nà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà fún ọkàn rẹ̀,+Kí ó sì lè kọ́ àwọn àgbàlagbà tirẹ̀ pàápàá ní ọgbọ́n.+ 23  Ísírẹ́lì sì wá sí Íjíbítì,+Jékọ́bù alára sì ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hámù.+ 24  Ó sì mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ máa so èso gidigidi,+Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sọ wọ́n di alágbára ńlá ju àwọn elénìní wọn.+ 25  Ó yí ọkàn-àyà wọn padà kí wọ́n lè kórìíra àwọn ènìyàn rẹ̀,+Kí wọ́n lè hùwà àlùmọ̀kọ́rọ́yí sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 26  Ó rán Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀,+Áárónì tí ó yàn.+ 27  Wọ́n gbé ọ̀ràn àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ kalẹ̀ láàárín wọn,+Àti àwọn iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hámù.+ 28  Ó rán òkùnkùn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ilẹ̀ ṣú;+Wọn kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 29  Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,+Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ikú pa ẹja wọn.+ 30  Àwọn àkèré ń gbáyìn-ìn ní ilẹ̀ wọn,+Ní yàrá inú lọ́hùn-ún ti àwọn ọba wọn. 31  Ó sọ pé kí àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ wọlé wá,+Àti kòkòrò kantíkantí ní gbogbo ìpínlẹ̀ wọn.+ 32  Ó sọ eji wọwọ wọn di yìnyín,+Àti iná tí ń jó fòfò lórí ilẹ̀ wọn.+ 33  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,Ó sì ṣẹ́ àwọn igi ìpínlẹ̀ wọn.+ 34  Ó sọ pé kí àwọn eéṣú wọlé wá,+Àti irú àwọn eéṣú kan, àní àwọn tí kò níye.+ 35  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ wọn;+Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí jẹ èso ilẹ̀ wọn. 36  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá gbogbo àkọ́bí tí ó wà ní ilẹ̀ wọn balẹ̀,+Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ gbogbo agbára ìbímọ wọn.+ 37  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú wọn jáde, ti àwọn ti fàdákà àti wúrà;+Kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ẹ̀yà rẹ̀ tí ń kọsẹ̀ lórí ìrìn. 38  Íjíbítì yọ̀ nígbà tí wọ́n jáde lọ,Nítorí pé ìbẹ̀rùbojo wọn ti mú wọn.+ 39  Ó na àwọsánmà kan fún àtabojú,+Àti iná láti pèsè ìmọ́lẹ̀ ní òru.+ 40  Wọ́n béèrè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àparò wá fún wọn,+Ó sì ń fi oúnjẹ láti ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.+ 41  Ó ṣí àpáta, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn jáde;+Èyí gba àwọn ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi kọjá gẹ́gẹ́ bí odò.+ 42  Nítorí tí ó rántí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 43  Nítorí náà, ó fi ayọ̀ ńláǹlà mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde,+Ó fi igbe ìdùnnú mú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde.+ 44  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+Wọ́n sì ń gba èso iṣẹ́ àṣekára àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè,+ 45  Kí wọ́n lè máa pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́,+Kí wọ́n sì máa kíyè sí àwọn òfin rẹ̀.+Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé