Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 103:1-22

Ti Dáfídì. 103  Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi,+ Àní ohun gbogbo tí ń bẹ nínú mi, fi ìbùkún fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.+   Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi, Má sì gbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀,+   Ẹni tí ń dárí gbogbo ìṣìnà rẹ jì,+ Ẹni tí ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn,+   Ẹni tí ń gba ìwàláàyè rẹ padà kúrò nínú kòtò,+ Ẹni tí ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú dé ọ ládé,+   Ẹni tí ń fi ohun rere tẹ́ ọ lọ́rùn ní ìgbà ayé rẹ;+ Ìgbà èwe rẹ ń sọ ara rẹ̀ dọ̀tun gẹ́gẹ́ bí ti idì.+   Jèhófà ń mú àwọn ìṣe òdodo ṣẹ ní kíkún+ Àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ń lù ní jìbìtì.+   Ó sọ àwọn ọ̀nà rẹ̀ di mímọ̀ fún Mósè,+ Àní ìbálò rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+   Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́,+ Ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.+   Òun kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo,+ Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 10  Òun kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa;+ Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa.+ 11  Nítorí pé bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé,+ Bẹ́ẹ̀ ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ga lọ́lá sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.+ 12  Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn,+ Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa.+ 13  Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀,+ Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.+ 14  Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa,+ Ó rántí pé ekuru ni wá.+ 15  Ní ti ẹni kíkú, àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bí ti koríko tútù;+ Bí ìtànná orí pápá ni bí ó ṣe ń yọ ìtànná.+ 16  Nítorí pé ẹ̀fúùfù lásán yóò fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀, kò sì sí mọ́;+ Ipò rẹ̀ kì yóò sì mọ̀ ọ́n mọ́.+ 17  Ṣùgbọ́n inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà jẹ́ láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin+ Sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,+ Àti òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ-ọmọ,+ 18  Sí àwọn tí ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́+ Àti sí àwọn tí ó rántí àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ̀ láti máa pa wọ́n mọ́.+ 19  Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọ̀run gan-an;+ Àkóso rẹ̀ sì ń jọba lórí ohun gbogbo.+ 20  Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì+ rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́,+ Nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 21  Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀,+ Ẹ̀yin òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.+ 22  Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin iṣẹ́ rẹ̀,+ Ní gbogbo ibi tí ó ń jọba lé.+ Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé