Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 102:1-28

Àdúrà ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó di ahẹrẹpẹ, tí ó sì tú ìdàníyàn rẹ̀ jáde níwájú Jèhófà tìkára rẹ̀.+ 102  Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;+ Ọ̀dọ̀ rẹ sì ni kí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ wá.+   Má fi ojú rẹ pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí mo bá wà nínú hílàhílo.+ Dẹ etí sí mi;+ Ní ọjọ́ tí mo bá pè, ṣe wéré, dá mi lóhùn.+   Nítorí pé àwọn ọjọ́ mi ti wá sí òpin gẹ́gẹ́ bí èéfín,+ Àní egungun mi ni a ti mú kí ó gbóná yoyo gẹ́gẹ́ bí ibi ìdáná.+   Ọkàn-àyà mi ni a ti kọlù gẹ́gẹ́ bí ewéko, ó sì gbẹ dànù,+ Nítorí pé mo ti gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.+   Nítorí ìró ìmí ẹ̀dùn mi,+ Egungun mi ti lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi.+   Mo jọ ẹyẹ òfú tí ń bẹ ní aginjù.+ Mo dà bí òwìwí kékeré tí ń bẹ ní àwọn ibi ahoro.   Mo ti rù hangogo, Mo sì dà bí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé.+   Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí.+ Àwọn tí ń mú kí n ṣe bí òmùgọ̀ ti fi èmi pàápàá búra.+   Nítorí pé mo ti jẹ eérú bí ẹní jẹ oúnjẹ;+ Àwọn ohun tí mo ń mu ni mo sì ti da ẹkún pàápàá pọ̀ mọ́,+ 10  Nítorí ìdálẹ́bi rẹ àti ìkannú rẹ;+ Nítorí pé ìwọ ti gbé mi sókè, kí o lè sọ mí nù.+ 11  Àwọn ọjọ́ mi dà bí òjìji tí ń pa rẹ́ lọ,+ Èmi alára sì gbẹ dànù bí ewéko lásán-làsàn.+ 12  Ní tìrẹ, Jèhófà, ìwọ yóò máa gbé fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Ìrántí rẹ yóò sì máa wà ní ìran dé ìran.+ 13  Ìwọ tìkára rẹ yóò dìde, ìwọ yóò ṣàánú fún Síónì,+ Nítorí pé ó jẹ́ àsìkò láti ṣe ojú rere sí i, Nítorí pé àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti dé.+ 14  Nítorí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní ìdùnnú sí àwọn òkúta rẹ̀,+ Wọ́n sì yí ojú rere wọn sí ekuru rẹ̀.+ 15  Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà,+  Gbogbo ọba ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù ògo rẹ.+ 16  Nítorí ó dájú pé Jèhófà yóò gbé Síónì ró;+ Òun yóò fara hàn nínú ògo rẹ̀.+ 17  Ó dájú pé òun yóò yíjú sí àdúrà àwọn tí a kó gbogbo nǹkan ìní wọn lọ,+ Kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àdúrà wọn.+ 18  Èyí ni a kọ̀wé rẹ̀ fún ìran ẹ̀yìn ọ̀la;+ Àwọn ènìyàn tí a óò dá yóò sì máa yin Jáà.+ 19  Nítorí pé ó ti bojú wolẹ̀ láti ibi gíga mímọ́ rẹ̀,+ Àní láti ọ̀run ni Jèhófà tìkára rẹ̀ ti wo ilẹ̀ ayé,+ 20  Láti gbọ́ ìmí ẹ̀dùn ẹlẹ́wọ̀n,+ Láti tú àwọn tí a yàn kalẹ̀ fún ikú;+ 21  Kí a lè polongo orúkọ Jèhófà ní Síónì+ Àti ìyìn rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù,+ 22  Nígbà tí a bá kó gbogbo ènìyàn jọ pa pọ̀,+ Àti àwọn ìjọba láti máa sin Jèhófà.+ 23  Ó ṣẹ́ agbára mi níṣẹ̀ẹ́ lójú ọ̀nà,+ Ó ké àwọn ọjọ́ mi kúrú.+ 24  Mo sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, Má ṣe mú mi kúrò ní ààbọ̀ àwọn ọjọ́ mi;+ Jálẹ̀jálẹ̀ ìran-ìran ni àwọn ọdún rẹ.+ 25  Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni ìwọ ti fi àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,+ Ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+ 26  Àwọn tìkára wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ tìkára rẹ yóò máa wà nìṣó;+ Àti gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, gbogbo wọn yóò gbó.+ Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, ìwọ yóò pààrọ̀ wọn, wọn yóò sì lo ìgbà wọn parí.+ 27  Ṣùgbọ́n bákan náà ni ìwọ wà, àwọn ọdún rẹ kì yóò sì parí.+ 28  Ọmọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò máa wà láàyè nìṣó;+ A ó sì fìdí àwọn ọmọ wọn múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in níwájú rẹ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé