Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 101:1-8

Ti Dáfídì. Orin atunilára. 101  Ṣe ni èmi yóò máa kọrin nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìdájọ́.+ Ìwọ, Jèhófà, ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí.+   Ṣe ni èmi yóò máa fi ọgbọ́n inú hùwà lọ́nà àìlálèébù.+ Ìgbà wo ni ìwọ yóò tọ̀ mí wá?+ Èmi yóò máa rìn káàkiri nínú ìwà títọ́ ọkàn-àyà mi nínú ilé mi.+   Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi.+ Èmi kórìíra ìgbòkègbodò àwọn tí ó ti yapa;+ Kì í dìrọ̀ mọ́ mi.+   Ọkàn-àyà wíwọ́ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi;+ Èmi kò mọ ohun búburú kankan.+   Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fọ̀rọ̀ èké ba alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ jẹ́ ní ìkọ̀kọ̀,+ Òun ni èmi ń pa lẹ́nu mọ́.+ Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ojú ìrera àti ọkàn-àyà ìṣefọ́ńté,+ Òun ni èmi kò lè fara dà.+   Ojú mi ń bẹ lára àwọn olùṣòtítọ́ ilẹ̀ ayé,+ Kí wọ́n lè máa bá mi gbé.+ Ẹni tí ń rìn lọ́nà àìlálèébù,+ Òun ni yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi.+   Kò sí oníṣẹ́ àgálámàṣà tí yóò máa gbé inú ilé mi.+ Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣèké, òun kì yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in+ Ní iwájú mi.+   Òròòwúrọ̀ ni èmi yóò máa pa gbogbo àwọn ẹni burúkú ilẹ̀ ayé lẹ́nu mọ́,+ Láti ké gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́+ kúrò nínú ìlú ńlá+ Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé