Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 100:1-5

Orin atunilára ti ìdúpẹ́.+ 100  Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.+   Ẹ fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà.+ Ẹ fi igbe ìdùnnú wọlé wá síwájú rẹ̀.+   Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run.+ Òun ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa.+ Àwa ni ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá ìjẹko rẹ̀.+   Ẹ wá sí àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ìdúpẹ́,+ Sínú àwọn àgbàlá rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ìyìn.+ Ẹ fi ọpẹ́ fún un, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀.+   Nítorí pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+ Inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Àti ìṣòtítọ́ rẹ̀ láti ìran dé ìran.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé