Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 10:1-18

ל [Lámédì] 10  Jèhófà, èé ṣe tí ìwọ fi dúró lókèèrè réré?+ Èé ṣe tí ìwọ fi ara rẹ pa mọ́ ní àwọn àkókò wàhálà?+   Nínú ìrera rẹ̀, kíkankíkan ni ẹni burúkú ń lépa ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́;+ A mú wọn nípasẹ̀ àwọn èrò-ọkàn tí wọ́n ti gbìrò.+   Nítorí pé ẹni burúkú ti yin ara rẹ̀ nítorí ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan ti ọkàn rẹ̀,+ Ẹni tí ń jẹ èrè àìyẹ+ sì ti súre fún ara rẹ̀;נ [Núnì]Kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà.+   Ẹni burúkú, gẹ́gẹ́ bí ìruga rẹ̀, kò ṣe ìwádìí kankan;+ Gbogbo èrò-ọkàn rẹ̀ ni pé: “Kò sí Ọlọ́run.”+   Àwọn ọ̀nà rẹ̀ ń láásìkí ní gbogbo ìgbà.+ Àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ ga sókè ré kọjá sàkáání rẹ̀;+ Ní ti gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí i, ó ń wú fùkẹ̀ sí wọn.+   Ó wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “A kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n;+ Láti ìran dé ìran, èmi yóò jẹ́ ẹni tí kò sí nínú ìyọnu àjálù kankan.”+ פ [Péè]   Ẹnu rẹ̀ kún fún ìbúra àti fún ẹ̀tàn àti fún ìnilára.+ Ìjàngbọ̀n àti ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.+   Ó jókòó ní ibùba àwọn ibi ìtẹ̀dó; Àwọn ibi tí ó lùmọ́ ni yóò ti pa aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.+ ע [Áyínì]Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ aláìrìnnàkore lójú méjèèjì.+   Ó ń lúgọ sí ibi tí ó lùmọ́ bí kìnnìún ní ibi kọ́lọ́fín rẹ̀.+ Ó ń lúgọ+ láti fipá gbé ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ lọ. Ó ń fipá gbé ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ lọ nígbà tí ó bá fa àwọ̀n rẹ̀ dí.+ 10  A tẹ̀ ẹ́ rẹ́, ó tẹrí ba, Ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn tí ó dorí kodò yóò sì wá bọ́ sínú àwọn èékánná rẹ̀ lílágbára.+ 11  Ó wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé:+ “Ọlọ́run ti gbàgbé.+ Ó ti fi ojú rẹ̀ pa mọ́.+ Dájúdájú, òun kì yóò rí i láé.”+ ק [Kófì] 12  Dìde,+ Jèhófà. Ọlọ́run, gbé ọwọ́ rẹ sókè.+ Má gbàgbé àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+ 13  Èé ṣe tí ẹni burúkú kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run?+ Ó wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “Ìwọ kì yóò béèrè fún ìjíhìn.”+ ר [Réṣì] 14  Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ ti rí ìjàngbọ̀n àti pákáǹleke. Ìwọ ń wò, kí o lè fi wọ́n lé ọwọ́ ara rẹ.+ Ìwọ ni aláìrìnnàkore,+ ọmọdékùnrin aláìníbaba, fi ara rẹ̀ lé lọ́wọ́. Ìwọ tìkára rẹ ti di olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.+ ש [Ṣínì] 15  Ṣẹ́ apá ẹni burúkú àti ẹni búburú.+ Kí o máa wá ìwà burúkú rẹ̀ títí ìwọ kì yóò fi rí i mọ́.+ 16  Jèhófà ni Ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+ Àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+ ת [Tọ́ọ̀] 17  Ìwọ, Jèhófà, yóò gbọ́ ìfẹ́-ọkàn àwọn ọlọ́kàn tútù dájúdájú.+ Ìwọ yóò múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀.+ Ìwọ yóò dẹ etí sílẹ̀,+ 18  Láti ṣe ìdájọ́ ọmọdékùnrin aláìníbaba àti ẹni tí a ni lára,+ Kí ẹni kíkú tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ má bàa máa fa ìwárìrì mọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé