Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 1:1-6

1  Aláyọ̀+ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú,+Tí kò sì dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+Tí kò sì jókòó ní ìjókòó àwọn olùyọṣùtì.+   Ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà,+Ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.+   Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi,+Tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀+Èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ,+Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.+   Àwọn ẹni burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,Ṣùgbọ́n wọ́n dà bí ìyàngbò tí ẹ̀fúùfù ń gbá lọ.+   Ìdí nìyẹn tí àwọn ẹni burúkú kì yóò fi dìde dúró nínú ìdájọ́,+Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò dìde dúró ní àpéjọ àwọn olódodo.+   Nítorí pé Jèhófà mọ ọ̀nà àwọn olódodo,+Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí í ṣe ti àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé